Ijọba Eko ti wọgi le ofin konilegbele patapata,wọn ni araalu le jade bo ṣe wu wọn

Faith Adebọla, Eko

Ofin konilegbele tawọn eleebo n pe ni kọfiu (curfew) tijọba Eko paṣẹ rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to lọ lọhun-un ni wọn ti wọgi le bayii, wọn ti ni konikaluku maa lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ rẹ bo ṣe fẹ, ati bo ṣe wu u.

Gomina Babajide Sanwo-Olu lo wọgi le ofin konilegbele naa lọjọ Abamẹta, Satide, o ni ẹri ti fihan pe omi alaafia ipinlẹ Eko tawọn janduku kan daru tẹlẹ ti bẹrẹ si i toro bayii, eyi lo mu koun wọgi le kọfiu naa.

Kọmiṣanna eto iroyin ati ọgbọn-inu, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ, to sọ ọrọ yii di mimọ sọ pe gomina ti fi da awọn olugbe ipinlẹ Eko loju pe aabo to peye maa wa fun wọn, tori gbogbo awọn agbofinro ati awọn ẹṣọ oju popo ti pada sẹnu iṣẹ wọn lati ri i daju pe ohun gbogbo n lọ bo ṣe yẹ nipinlẹ naa.

Gomina waa rọ gbogbo araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, ki alaafia ati aabo le wa, ki wọn ma si ṣe tun da ọwọ aago pada sẹyin mọ, o ni kawọn eeyan tete taṣiiri ẹnikẹni ti wọn ba kẹẹfin pe o n huwa tabi sọrọ to tun le da yanpọnyanrin silẹ fawọn agbofinro.

Tẹ o ba gbagbe, ofin konilegbele naa waye latari rukerudo to ṣẹ yọ nigba tawọn janduku kan ja iwọde tawọn ọdo n ṣe ta ko ọlọpaa SARS gba mọ wọn lọwọ, ti wọn si n da omi alaafia ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ mi-in ni Naijiria ru.

Leave a Reply