Ijọba Eko yoo ṣi ileewe alakọọbẹrẹ ati girama lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an

Faith Adebọla

Idunnu ti ṣubu lu ayọ fawọn akẹkọọ lawọn ile-ẹkọ jake-jado ipinlẹ Eko pẹlu bi Gomina ipinlẹ ọhun, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ṣe kede nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, pe gbogbo ile-ẹkọ nipinlẹ naa maa ṣi fun ikẹkọọ lakọtun ninu oṣu kẹsan-an ọdun yii.

Nibi ipade pẹlu awọn akọroyin to waye nile ijọba to wa ni Marina, l’Ekoo, ni gomina ti sọrọ naa di mimọ.

Sanwo-Olu ni: “Inu mi dun lati kede pe awọn ileewe giga wa yoo si fun ikẹkọọ bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an, gbogbo ile-ẹkọ giga pata.”

Lara awọn ile-ẹkọ naa ni fasiti, poli atawọn kọlẹẹji to kaakiri ipinlẹ ọhun.

Gomina tun tẹ siwaju pe awọn ileewe pamari ati sẹkọndri yoo lanfaani lati bẹrẹ eto ẹkọ tiwọn naa pada lati ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an yii, kan naa, iyẹn lẹyin tawọn to n ṣe idanwo aṣekagba Wayẹẹki to n lọ lọwọ yii ba ti pari idanwo wọn lọjọ keji, oṣu ọhun.

Leave a Reply