Ijọba Eko yoo fiya jẹ olukọ to ba ṣe lẹsinni fawọn ọmọ ileewe

Adewale Adeoye

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Eko ti fajuro gidi si bawọn tiṣa ileewe kan ṣe n kan an nipa fawọn akẹkọọ ileewe wọn pe ki wọn maa waa ṣe lẹsinni ọsan ninu ọgba ileewe wọn lasiko to yẹ kawọn akẹkọọ ọhun maa kọpa ninu eto pataki mi-in. Wọn ni olukọ yoowu tawọn ba gba mu pe o n gbowo lọwọ awọn akẹkọọ rẹ lati ṣe lẹsinni ọsan fun wọn yoo jiyan rẹ niṣu. Aago mẹjọ aarọ ni ijọba ipinlẹ Eko fọwọ si pe ki eto ẹkọ bẹrẹ ni gbogbo ileewe, ki wọn si pari ẹkọ fawọn akẹkọọ wọn ni aago meji ọsan, ki wọn fawọn akẹkọọ ileewe wọn lanfaani wakati kan gbako lati darapọ mọ ẹgbẹ alaaanu bii bii Boys-Scott, Boys/ Girls Brigade, Debate ati bẹẹ bẹẹ lọ. ALAROYE gbọ pe ọpọ awọn tiṣa lawọn ileewe ijọba Eko ni wọn maa n kan an nipa fawọn akẹkọọ wọn pe ki wọn waa ṣe lẹsinni lasiko to yẹ kawọn akẹkọọ ọhun darapọ mọ awọn ẹgbẹ wọn gbogbo fun ẹgbẹ yoowu ti wọn ba nifẹẹ si. Kọmiṣanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Eko, Ọnarebu Jamiu Tolani Alli Balogun, to sọrọ ọhun di mimọ nibi ṣiṣi ileewe igbalode oniyara pupọ kan ati aga ijokoo ti ajọ aladaani kan, ‘Grimaldi Group and the Ports Terminal Multi Services LTD’ kọ fawọn akẹkọọ ileewe ‘Amuwo Ọdọfin Junior High School’ to wa nijọba ibilẹ idagbasoke Amuwo Ọdọfin, nipinlẹ Eko lo ti ṣe ikilọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii. Kọmiṣanna ọhun ni wakati kan tijọba Eko ya sọtọ fawọn akẹkọọ ṣe pataki pupọ fun wọn lati fi darapọ mọ ẹgbẹ yoowu ti wọn ba nifẹẹ si ju lọ nileewe wọn, ki i ṣe pe ki awọn tiṣa kan maa waa kan an nipa fun wọn pe wọn gbọdọ waa ṣe lẹsinni lọdọ wọn, ti wọn aa si maa gbowo lọwọ wọn. O rọ awọn olukọ gbogbo pe ki wọn ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lasiko ti wọn ba fi wa lẹnu iṣẹ.

Leave a Reply