Ijọba fẹẹ ka iye awọn eeyan to talaka ju lọ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ni eto kika iye eeyan ti oṣi ati iṣẹ n ba finra loju paali jake-jado origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Eko maa bẹrẹ. Igbesẹ yii maa waye lati leṣẹẹ-lugbẹ lakọtun nipinlẹ naa.

Kọmiṣanna feto ọrọ aje ati iṣunna owo (Economic Planning and Budget) nipinlẹ Eko, Sam Egube, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ninu atẹjade kan ti Akọwe agba lọfiisi rẹ fi sode lorukọ ijọba ipinlẹ Eko.

O ni igbesẹ yii pọn dandan lati le mọ ipo ti eeyan kọọkan wa ni ti ọrọ aje, iṣuna owo, airina ati airilo, kijọba si le pinnu eto to maa ba ipo olululuku mu lati le gbọn oṣi ati iṣẹ danu lawujọ wa.

O lawọn oṣiṣẹ ajọ oluṣiro ipinlẹ Eko (Lagos Bereau of Statistics) yoo bẹrẹ si i lọ kaakiri ojule kọọkan lawọn ijọba ibilẹ ati kansu mẹtadinlaaadọta to wa l’Ekoo, lati wọọdu kan si ekeji, lati beere awọn ibeere ti wọn ti ṣeto sinu iwe ọwọ wọn.

O ni ọjọ mẹẹẹdọgbọn gbako ni wọn yoo fi ṣewadii ọhun, ojoojumọ si ni, bẹrẹ lati ọjọ kẹrinlelologun, oṣu yii.

O ṣalaye pe lẹyin ti iwadii ati onka yii ba ti pari ni wọn yoo ṣeṣiro lati mọ awọn ohun tijọba yoo ṣe sawọn agbegbe, wọọdu atijọba ibilẹ kọọkan ti yoo tubọ mu ọrọ aje rugọgọ si i fawọn eeyan, ti yoo si din iṣẹ oun oṣi ku.

Wọn waa rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati fọwọ sowọ pọ nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ naa ba de ọdọ wọn, ki wọn si fi suuru ati ootọ inu dahun awọn ibeere wọn, ki wọn le jẹ anfaani ijọba awa-ara-awa lọjọ iwaju

Leave a Reply