Ijọba fẹẹ mu Sunday Igboho ni gbogbo ọna

Faith Adebọla

Adiẹ ba le okun, ara o rọ okun, ara o si rọ adiẹ, lọrọ gbajugbaja ọkunrin ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Ṣunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho da funjọba ati ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa bayii, latari bi wọn ṣe n wa gbogbo ọna lati fi pampẹ ofin gbe e ju satimọle.

O kere tan, o ti di ẹẹmeji ọtọọtọ tawọn agbofinro ti gbe igbesẹ lati mu Sunday Igboho sahaamọ wọn, eyi to kẹyin ni ti lẹta ti ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa, IG Mohammed Adamu, kọ si ọkunrin naa l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, wọn ni wọn fẹẹ ri i ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, l’Abuja.

Ileeṣẹ akolẹta kan ti wọn kọkọ fi lẹta naa ran jiṣẹ fawọn ẹmẹwa Sunday nile rẹ to wa n’Ibadan, bo tilẹ jẹ pe awọn ẹmẹwa naa kọ lati gba lẹta ọhun lọwọ wọn, ẹyin eyi ni wọn lawọn ọlọpaa bii mẹẹẹdogun ya bo ile naa lọsan-an Ọjọbọ ọhun, wọn lọgaa awọn lo ran awọn niṣẹ lati fun Sunday Igboho ni lẹta. Mọto ayọkẹlẹ Toyota Corona kan lawọn kan lara wọn gbe wa.

Awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu Oloye Adeyẹmọ lo gba lẹta naa, wọn lawọn aa fi jiṣẹ fun un.

Nirọlẹ ọjọ naa ni amugbalẹgbẹẹ oniroyin rẹ, Ọlayọmi Koiki, kọ atẹjade kan lori iṣẹlẹ ọhun pe Sunday Igboho ko ni i yọju sẹnikan lasiko yii, wọn ni ki ọga ọlọpaa kọkọ kọwe pe awọn agbebọn atawọn Boko Haraamu ti wọn n ṣọṣẹ kaakiri, ti wọn si n pa tọmọde tagba lẹkun lori ilẹ wọn na.

Atẹjade naa fi kun un pe ki ọga ọlọpaa kede ni gbangba pe oun fẹ ki Sunday Igboho yọju soun, dipo ti yoo fi maa kọ lẹta labẹnu, tori awọn ṣi ranti bawọn kan ṣe fi lẹta oni-bọmbu pa Dele Giwa, gbajugbaja akọroyin ilẹ wa kan.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, lawọn ọlọpaa atawọn ọtẹlẹmuyẹ kan lọọ rẹbuu Sunday Igboho lagbegbe ibudokọ Guru Maharaji, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, diẹ lo ku ki wọn fi tipa tikuuku wọ ọkunrin naa lọ, ṣugbọn awọn ọdọ agbegbe naa ko jẹ ko ṣee ṣe fun wọn.

Ohun ta a gbọ ni pe ijọba apapọ atawọn alagbara oṣelu kan ni wọn n wà lé IG Adamu lọrun pe afi ko wa gbogbo ọna ti wọn yoo fi mu Sunday Igboho, paapaa latari bi ọkunrin naa ṣe kede laipẹ yii nibi ipade kan ti wọn ṣe niluu Ibadan lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, pe dandan ni ki ẹya Yoruba ya kuro lara Naijiria, o ni Yoruba maa ni orileede tiwọn, to pe ni Oduduwa Republic.

Olobo kan sọ pe latigba ti Sunday Igboho ti kede pe kawọn Fulani kẹru wọn kuro nilẹ Yoruba, ki wọn wabomi-in gba lọ, lawọn kan ti n dọdẹ ati mu ọkunrin naa, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa tun n bẹru ohun to le tidi ẹ yọ tiru nnkan bẹẹ ba ṣẹlẹ, tori ọgọọrọ ẹya Yoruba lo fara mọ igbesẹ Sunday Igboho, ti wọn gba tiẹ, ti wọn si n ṣatilẹyin fun un.

Wọn lawọn ọlọpaa n woye pe tawọn ba fi pampẹ ofin mu un sahaamọ, afaimọ ni ki yanpọnyanrin ma bẹ silẹ, eyi si le da omi alaafia gbogbo agbegbe ilẹ Yoruba ati ti orileede lapaapọ ru, idi niyẹn ti wọn fi fiwe pe e s’Abuja.

Amọ ṣa o, ọpọ awọn agbaagba ilẹ Yoruba ti da si igbesẹ tijọba fẹẹ gbe yii, bẹẹ ni wọn n laago ikilọ pe ọrọ naa le da wahala nla silẹ, ti ko si ni i yanju bọrọ.

Amofin agba ilẹ wa ati ajafẹtọọ ọmọniyan, Fẹmi Falana, sọ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, fawọn oniroyin pe ijọba o le mu Sunday Igboho lai kọkọ lọọ mu Shehu Gumi, aafaa ẹsin Islam to n ṣe agbodegba fawọn janduku agbebọn lapa Oke-Ọya.

Falana ni “Ijọba o le mu Sunday Igboho tori awọn ti wọn ti kede pe kawọn ẹya mi-in kuro lori ilẹ awọn naa lapa Oke-Ọya wa tijọba o mu wọn. Ṣhehu Gumi to n da iyapa ẹsin silẹ, to si n ṣe wọle-wọde pẹlu awọn agbebọn naa wa nibẹ, wọn gbọdọ kọkọ mu awọn yẹn na.’’

Bakan naa ni minisita fun igbokegbodo ọkọ ofurufu nigba kan, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, naa sọrọ ikilọ, o ni “Ohun to le tete da alaafia ati iṣọkan Naijiria ru, to le fọ gbogbo nnkan loju pọ, ni bawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ kan ṣe faake kọri pe dandan ni ki wọn mu ọrẹ mi ati arakunrin mi, Sunday Igboho sahaamọ. Aṣiṣe nla gbaa lo maa jẹ fun ijọba ti wọn ba fi dan iru ẹ wo.” Ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lo ti sọrọ ọhun lọjọ Eti.

Amofin agba mi-in, Oloye Ifẹdayọ Adedipẹ, sọ pe oun o ri ẹsẹ kan ninu bi Sunday Igboho ṣe kọ lati gba lẹta ipe ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa. O ni ko si nibi kan ninu iwe ofin ilẹ wa to sọ pe dandan ni keeyan gba ipe iru ipe bẹẹ, ko si sohun to buru nibẹ teeyan ba kọ ọ lori ipilẹ to nitumọ.

Leave a Reply