Ijọba fẹẹ pin mita miliọnu kan fun araalu lọfẹẹ

Aderoounmu Kazeem

Oni ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, ni ijọba orilẹ-ede yii sọ pe oun yoo ṣe ifilọlẹ pipin mita ina mọnamọna fun araalu lọfẹẹ.

Awọn ipinlẹ wọnyi: Eko, Kaduna ati Kano ni ijọba ti sọ pe awọn eeyan yoo ti lanfaani lati gba mita ina mọnamọna lọfẹẹ. Milọnu kan mita nijọba ti sọ pe oun yoo pin lọfẹẹ kaakiri awọn agbegbe yii.

Ọkan lara awọn to n ṣiṣẹ ni ọfiisi aarẹ ti sọ pe igbesẹ naa waye pẹlu ibamu si eto ti Aarẹ  Muhammadu Buhari ṣe lati fopin si wahala owo gọbọi ti wọn maa n gbe waa ka awọn eeyan mọle.

O ni awọn eeyan agbegbe Oṣodi, Ikẹja, Yabaa, Suurulere labẹ akoso Eko Disco nipinlẹ Eko ni yoo janfaani ọhun l’Ekoo, bẹẹ lawọn eeyan adugbo kan ni Kano ati Kaduna naa yoo lanfaani si mita ọfẹ ọhun pẹlu.

Ohun ti ALAROYE tun gbọ ni pe bii mita miliọnu mẹfa ni ileeṣẹ to wa nikawọ ẹ yoo ko sita laarin ọdun meji, eyi ti yoo fun awọn eeyan bii ọgbọn miliọnu lanfaani lati maa ri mita lo daadaa.

Ọgbẹni Laolu Akande, oluranlọwọ igbakeji Aarẹ ti sọ pe loootọ ni iroyin ọhun, ati pe o wa lara adehun to waye laarin ẹgbẹ oṣiṣẹ ati ijọba nigba ti ileeṣẹ mọnamọna fowo kun owo ina ọba ti araalu n lo.

Ohun ta a tun gbọ ni pe titi ipari ọdun yii ni wọn yoo pin mita miliọnu kan to wa nilẹ ọhun kari ibi ti ijọba ti ni in lọkan lati bẹrẹ ẹ bayii

 

Leave a Reply