Ijọba fofin de awọn alumọjiri to n tọrọ baara loju popo n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, nijọba ipinlẹ Kwara kede pe ki gbogbo awọn alumajiri ti wọn n tọrọ owo lawọn oju popo niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, tete kaasa wọn bayii.

Kọmisanna to n ri si idagbasoke awujọ, Arabinrin Abọsẹde Arẹmu, lo kede ọrọ naa niluu Ilọrin. O ni ijọba Kwara ti fofin de gbogbo awọn alumajiri ti wọn n gba baara lawọn opopona kan to ṣe pataki niluu naa. O tẹsiwaju pe ọpọ awọn to n tọrọ owo ọhun ni wọn jẹ Hausa to wa lati apa Oke-Ọya, orile-ede yii, ti ijọba si ti ṣe ipade pẹlu awọn asoju awọn Hausa ọhun, ti wọn  ti tọwọ bọwe adehun pe ki gbogbo awọn to n tọrọ owo naa tete fi oju popo silẹ ni kiakia.

O fi kun un pe ijiya wa fun ẹnikẹni ti wọn ba gba mu to n tọrọ owo loju popo lati wakati yii lọ. Awọn to ṣoju Hausa lọdọ ijọba ni Surajudeen Hussain, Rufai Sanni ati Mohammed Lawal, ti wọn si fi da ijọba loju pe ko ni i si Alumajiri kankan loju popo mọ.

Leave a Reply