Ijọba gbọdọ gba awọn ọlọpaa si i ti a ba fẹ ki wahala eto aabo dopin lorileede yii – Ọsinbajo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo, ti sọ pe ọkan pataki lara awọn ipenija to n koju orileede yii bayii ni aisi eto aabo to peye, o si ṣee ṣe lati koju ti ijọba ba le gba awọn ọlọpaa si i.
Yatọ si eyi, Ọsinbajo dabaa pe ki awọn ibudo ti wọn yoo ti maa pese awọn nnkan ija oloro to lagbara wa lorileede yii lati jẹ ọna abayọ si bi Naijiria ṣe n fi gbogbo igba lọọ ra awọn nnkan naa loke okun.
Lasiko ti Ọṣinbajo n ba awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun sọrọ niluu Oṣogbo, lọjọ Ẹti, Furaidee, lo sọ pe pẹlu iriri ati imọ ti oun ti ni labẹ Aarẹ Mohammadu Buhari gẹgẹ bii igbakeji, oun yoo ṣe gudugudu meje ti oun ba de ipo naa.
Ọṣinbajo ṣalaye pe, “Ko si nnkan ti Aarẹ Buhari fi pamọ fun mi nipa iṣejọba rara, emi naa si sin in pẹlu otitọ ati ododo lai fi ọbẹ ẹyin jẹ ẹ niṣu, eleyii fun mi lanfaani lati gbaradi fun iṣẹ ti mo jade fun.
“Nibi ti ọrọ iṣejọba orileede yii de bayii, yoo gba ẹni ti ko ni iriri lodidi ọdun meji ko too le mọ ibi to fẹẹ kọwọ bọ to ba de ipo aarẹ, ṣugbọn emi ti ni iriri kikun, ọjọ akọkọ ti mo ba debẹ ni iṣẹ yoo bẹrẹ lai ṣẹṣẹ maa yẹ faili wo.
“Ko si awọn kabaa (Cabal) kankan to le di mi lọwọ rara, nitori mo mọ bi ọga mi ṣe ṣe, mo si mọ gbogbo igbesẹ to tọ lati gbe nipa wọn.

“Ni ti iṣoro eto aabo ti a n koju lọwọlọwọ, ko si orileede ti ko ni ipenija tirẹ, ṣugbọn atunto nla gbọdọ wa ni ẹka eto aabo wa ti a ba fẹ ki opin de ba gbogbo wahala yii.

“Lakọọkọ, a gbọdọ ṣafikun iye awọn agbofinro wa, orileede yii fẹ pupọ, awọn oṣiṣẹ alaabo wa kere niye, a gbọdọ gba awọn ọlọpaa si i.
“Lọna keji, ko dara to bo ṣe jẹ pe oke-okun la ti n ra awọn nnkan ija ogun, o maa n to ọdun mẹrin lẹyin ti a ti sanwo ka too ri omi-in gba ninu wọn. Idi niyi ti awa naa fi gbọdọ ni ibi ti a ti maa maa ṣe awọn nnkan wọnyi”
Ṣaaju ni Oṣinbajo, ẹni ti Igbakeji Gomina ipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi, gba lalejo, ti kọkọ lọ si aafin Ataọja ti ilu Oṣogbo, nibẹ lo ti sọ pe oun loun kunju oṣunwọn ju laarin awọn oludije ninu ẹgbẹ APC pẹlu iriri ti oun ni gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ ati adele-aarẹ.

Leave a Reply