Ijọba ipinlẹ Ekiti fun awọn ẹlẹwọn mejila lominira 

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ninu eto iforiji ti ijọba ipinlẹ Ekiti gbe kalẹ lati ṣami ayẹyẹ ọdun Itunu aawẹ, ko din ni ẹlẹwọn mejila ti ijọba foriji, ti wọn si tu wọn silẹ pe ki wọn maa lọ sile wọn layọ ati alaafia.

Nigba to n tu awọn ẹlẹwọn naa silẹ ni gbagede ọgba ẹwọn to wa ni Opopona Afao, niluu Ado-Ekiti, Gomina Kayọde Fayẹmi ati awọn lọgaalọgaa lẹnu iṣẹ ijọba rẹ ni wọn wa ni ibi eto pataki naa.

Fayẹmi sọ pe iya ẹṣẹ bii ole, afọwọra ati ile fifọ lawọn ẹlẹwọn naa n jiya rẹ. O si ka orukọ wọn setiigbọ gbogbo awọn to wa nibi eto naa.

Orukọ awọn to gbominira ọhun ni: Akinyẹmi Faith, Romiluyi Fẹmi, Adebusuyi Deji, Philip Michael, Isa Kadere, Dayọ Julius ati Abiọdun Oluwatosin. Awọn yooku ni, Adubiaro Sunday, Oluwatimilẹyin Ọlanikuti, Stephen Jacob, Adewale Ojo ati Sunday Oluwaṣọla.

Gomina Fayẹmi gba wọn nimọran pe ki wọn jẹ ọmọluabi bi wọn ṣe gba iyọnda, ki wọn ma si ṣe ohun ti yoo gbe wọn pada wa si ọgba ẹwọn naa.

Fayemi juwe iforiji naa gẹgẹ bii eto pataki ti ijọba rẹ gbe kalẹ lati fi oju aanu wo awọn to ṣẹ ẹṣẹ kekere, ati awọn ti ẹṣẹ wọn ko lagbara pupọ.

Ṣaaju ni Kọmiṣanna fun eto idajọ nipinlẹ naa, Ọgbẹni Ọlawale Fapounda, ti sọ pe oun ba awọn ẹlẹwọn to gba iyọnda naa yọ, gẹgẹ bi wọn ṣe ri iforiji gba lati ọdọ ijọba, o gba wọn nimọran pe ki wọn jẹ ọmọ jẹẹjẹ bi wọn ṣe n darapọ mọ awujọ.

Ọkan lara awọn ẹlẹwọn naa, Ọgbẹni Adunbiaro Sunday, to jẹ ẹni ọdun mejilelọgọta to gba iyọnda sọ fawọn oniroyin nibi eto naa pe oun dupẹ pupọ lọwọ ijọba ipinlẹ Ekiti lori aforiji naa.

O ṣalaye pe ẹrọ ilewọ, iyẹn foonu, loun ji toun fi di ero ọgba ẹwọn naa, o si ṣeleri pe oun ko ni i pada sinu ẹṣẹ naa mọ.

Leave a Reply