Ijọba ipinlẹ Eko ṣi ileewe Chrisland pada

Monisola Saka
Ijọba ipinlẹ Eko, latọwọ ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ n’ipinlẹ Eko, ti buwọ lu ṣiṣi gbogbo ẹka ileewe Chrisland ti wọn ti ti pa tẹlẹ latari iwa aitọ ti awọn akẹkọọ kan hu pada.
Kọmiṣanna feto ẹkọ n’ipinlẹ Eko, Arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ, kede ọrọ yii ninu atẹjade kan lọjọ Satide.
Ijọba ti ti gbogbo ẹka ileewe Chrisland pa lati ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022, latari iwa ko-tọ kan ti awọn akẹkọọ ẹka ti Victoria Garden City hu lasiko ti wọn lọ si Dubai fun idije kan ti wọn n pe ni ‘World School Games’ laarin ọjọ kẹwaa si ikẹtala, oṣu Kẹta ọdun 2022.
Lori iṣẹlẹ yii ni awọn alaṣẹ ileewe ọhun fi da ọmọbinrin tọrọ kan ọhun duro sile, wọn ni oun gan-an ni ọga laarin awọn ti wọn huwa adojutini ọhun.
Ijọba ni igbimọ awọn obi ati olukọ ileewe ọhun yoo maa ṣiṣẹ itọsọna to jẹ mọ ọpọlọ ati iṣẹ inu awujọ (psychosocial support) fun awọn akẹkọọ ti wọn jọ huwa aidaa ọhun.
Ninu atẹjade ọhun ni Kọmiṣanna feto ẹkọ ti ni “Ileeṣẹ eto ẹkọ ijọba ipinlẹ Eko ti ni lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ki awọn alaṣẹ lẹka tọrọ kan ṣi gbogbo ẹka ileewe Chrisland ti wọn ti ti pa nitori iwa ko-tọ ti awọn akẹkọọ ileewe naa hu ni Dubai.
” Aṣẹ ti ijọba pa yii waye lẹyin ọpọlọpọ iwadii to munadoko ti awọn alaṣẹ ti ṣe. Yatọ si eyi, wọn ṣe eyi ki idiwọ ma baa si fun awọn akẹkọọ lori ẹkọ wọn gẹgẹ bi wọn ṣe fẹẹ bẹrẹ saa ẹkọ tuntun lọjọ Mọnde ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ta a wa yii.

” Ijọba ipinlẹ Eko ti ileewe ọhun pa fun aabo awọn akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ lati ri i daju pe ko si idiwọ kankan lasiko iwadii iṣẹlẹ naa.

” Ileeṣẹ eto ẹkọ atawọn ileeṣẹ ipinlẹ Eko mi-in, pẹlu ajọṣepọ igbimọ awọn obi ati olukọ yoo jọ ṣiṣẹ papọ lori itọsọna nipa imọ to je mọ ọpọlọ ati iṣesi awujọ ti wọn ti la kalẹ lori awọn akẹkọọ.

“Wọn tun ṣayẹwo awọn eto ile ẹkọ ọhun finnifinni, paapaa ju lọ lori ijade ati irinajo kuro layiika ile ẹkọ, wọn ri i daju pe eto aabo wa nilẹ lati dena iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.

” Bakan naa, ileeṣẹ eto ẹkọ yoo ṣe ifilọlẹ ofin ati ilana ti atunṣe ti ba fun gbogbo ileewe ijọba ati ti aladaani jake-jado ipinlẹ Eko titi oṣu to n bọ “.

Leave a Reply