Ijọba ipinlẹ Eko gbẹsẹ le ilẹ ile alaja mọkanlelogun to wo n’Ikoyi

Monisọla Saka
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nijọba ipinlẹ Eko sọ pe awọn ti gba ilẹ ti wọn kọle alaja mọkanlelogun to wo n’Ikoyi si.
Kọmiṣanna feto agbegbe ati amojuto ile igbalode, (Physical Planning and Urban Development) Dokita Idris Salakọ, to sọ eleyii di mimọ ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Eko fẹẹ gbẹsẹ le ilẹ ọhun ni ibamu pẹlu eto ile kikọ to sọ pe, ẹni yoowu to ba ni ile to ba da wo yoo jọwọ rẹ silẹ fun ijọba ipinlẹ ọhun ni.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ijọba o ti i gbe igbesẹ lori ohun ti wọn fẹẹ fi ilẹ ọhun ṣe, ṣugbọn nigbakuugba ti wọn yoo ba lo o, wọn yoo fi ṣe nnkan ti yoo maa mu ni ranti awọn ti wọn ba iṣẹlẹ ile wiwo naa lọ ni.
Nigba to n sọrọ lori bi wọn ṣe fẹẹ fa ile wiwo naa le awọn onimọ ẹrọ ti yoo wo o tan lọwọ, Salakọ sọ pe awọn ni lati fi awọn araalu atawọn to n gbe ile naa sọkan tawọn ba maa wo o.
Ninu ọrọ tiẹ, Kọmiṣanna fun awọn iṣẹ akanṣe atawọn ọrọ to kan awọn ileeṣẹ ijọba, Tayọ Bamgboṣe-Martins, sọ pe, ijọba o ni nnkan kan an ṣe pẹlu awọn ti wọn fowo gba yara tabi irufẹ ojule yoowu ninu ile to wo yii, idi si niyi ti ijọba ipinlẹ Eko ko fi ni i le fun wọn lowo gba-ma-binu.
Ni ti Kọmiṣanna feto iroyin, Gbenga Ọmọtọṣọ, o sọ pe ko si ohun meji tawọn ni lati ṣe ju ki wọn wo ile naa lọ, nitori ko si abajade to daa ninu gbogbo ayẹwo ti wọn ṣe lori ẹ.
O fi kun un pe ijọba yoo fi awọn eeyan sọkan ninu igbesẹ yoowu ti wọn ba fẹẹ gbe, o ṣalaye siwaju pe, awọn ti ṣe ipade pẹlu awọn ti ọrọ kan atawọn to n gbe ninu ile naa pẹlu awọn tọrọ kan labala eto ile kikọ.
Ọmọtọṣọ waa ni ki awọn eeyan dakẹ jẹẹjẹ fun iṣẹju kan lorukọ awọn to ba iṣẹlẹ buburu naa rin.
Alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Edge and Designs, Theophilus Lewo, ni ile wiwo ọhun le gba awọn to aadọrun-un ọjọ, ṣugbọn o ṣee ṣe ki awọn sun un siwaju nitori oju ọjọ, ojo ati igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ awọn. O ni kii ṣe pe ileeṣẹ awọn n bọ lati da ile naa wo, ṣugbọn ohun ti awọn fẹẹ ṣe ni lati fi ọgbọn wo awọn ibi ti ko yẹ.

Leave a Reply