Ijọba Eko tun fofin de ọkada lawọn ijọba ibilẹ mẹrin mi-in

Monisọla Saka, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti tun paṣẹ pe ki iṣẹ ọkada ṣiṣe tun kasẹ nilẹ lawọn ijọba ibilẹ mẹrin atawọn ijọba kansu (local council) nipinlẹ ọhun, bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Ki a ranti pe, lọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye lori ijamba ti ọkada n ṣe, atawọn iwa ẹranko ti awọn ọlọkada yii n hu ni gomina Sanwo-Olu fofin de ọkada lawọn ijọba ibilẹ mẹfa ati ijọba agbegbe mẹsan-an, lati tọwọ ọmọ iwakiwa awọn ọlọkada yii bọṣọ.

Ta o ba gbagbe, lọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2021, ni gomina ipinlẹ Eko ṣe atunṣe si ofin oju popo to de ọkada wiwa nipinlẹ naa. Lẹyin ti awọn gomina ti wọn gbe ijọba silẹ fun un, Babatunde Fashola ati Akinwunmi Ambọde, ti kọkọ gbegi le ọkada gigun l’Ekoo.

Awọn ijọba ibilẹ mẹrin tọrọ kan bayii ni: Koṣọfẹ, Shomolu, Oshodi-Isọlọ, Mushin ati gbogbo awọn ijọba kansu to ba wa labẹ agbegbe koowa wọn.

Awọn ijọba agbegbe wọnyi ni, Ikosi-Ishẹri ati Agboyi-Ketu, labẹ ijọba ibilẹ Koṣọfẹ, Isọlọ, Bariga, labẹ Shomolu ati Odi-Olowo, labẹ ijọba ibilẹ Mushin.

Leave a Reply