Ijọba ipinlẹ Eko yoo tọju ọmọ ti Mohbad fi saye lọ-Ọbafẹmi Hamzat

Jamiu Abayomi

Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Ọbafẹmi Hamzat, ti ṣeleri pe ijọba awọn yoo tọju ọmọ oṣu marun-un ti ọmọkunrin olorin hipọọpu to ku laipẹ yii, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba ti gbogbo eeyan mọ si Mohbad fi saye lọ.

Ọbafẹmi sọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an yii, lasiko to ṣabẹwo si iya to bi ọmọkunrin olorin naa. O ni fi da awọn mọlẹbi naa loju pe gbogbo igbeṣẹ lawọn n gbe lati ṣe iwadii lori iku to pa ọmọkunrin naa. Bẹẹ lo ni awọn to lọwọ ninu rẹ ko ni i lọ lai jiya.

Igbakeji gomina yii tun ṣeleri pe ijọba yoo mojuto itọju ọmọkunrin ti Mohbad fi saye lọ, Liam Imọlẹ.

Bakan naa lo rọ awọn alatilẹyin ọmọkunrin olorin yii lati se suuru,  o ni loootọ loun mọ pe awọn ọmọ Naijiria

Lati mu ki idajọ ododo waye, ki ọwọ si tẹ awọn ti wọn ba lọwọ ninu iku ojiji to pa ọdọmọde olorin yii, lai ṣegbe lẹyin ẹni kan lo mu ki Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ke si ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ,  ‘Department of State Service’ (DSS), lati darapọ mọ awọn ti yoo kopa ninu iwadii to fara sin lori iku oloogbe naa.

Gomina sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto iroyin ati ọgbọn inu nipinlẹ Eko, Gbenga Ọmọtọsọ, fọwọ si, to si fi lede lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.

Ninu atẹjade naa nijọba ipinlẹ Eko ti ba awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn ololufẹ oloogbe naa kẹdun ipapoda eeyan wọn.

Sanwo-Olu  tun lo akoko naa lati ke si si ẹnikẹni to ba ni ẹri tabi ohunkohun pataki kan to ba le ran iwadii naa lọwọ lati tọ ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ (DSS), yii lọ, ki iwadii naa le rọrun.

“Ijọba waa rawọ ẹbẹ si awọn oluwadii yii lati fi aṣiri ati aabo to gbopọn bo gbogbo awọn ẹlẹrii to ba wa siwaju wọn pẹlu alaye pataki tabi ẹri itọkasi ti o le ṣe iranlọwọ fun iwadii naa” .

“A mọ awọn irora ati adanu ti iku ọdọmọkunrin to ni afojusun ati ileri ọjọọla to dara funra rẹ yii maa jẹ fun awọn eeyan rẹ, pẹlu bo ṣe tiraka wa orukọ fun ara rẹ ni ninu iṣẹ ti ifigagbaga wa yii. Ki Ọlọrun fun ẹmi rẹ ni isinmi, ko si tu awọn ẹbi ati awọn ololufẹ rẹ ninu”.

Lati igba ti iṣẹlẹ iku ojiji ọmọkunrin naa ti gbode kan, lawọn ololufẹ orin rẹ ti pe fun iwadii to peye lori iku to pa ọmọkunrin olorin naa.

 

Leave a Reply