Ijọba ipinlẹ Ọṣun kede igbele nijọba ibilẹ mẹrin

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Latari bi arun koronafairọọri ṣe n fojoojumọ gbilẹ niluu Ileṣa, Gomina Gboyega Oyetọla ti kede pe kawọn ijọba ibilẹ mẹrin kan nibẹ bẹrẹ igbele ni kiakia.

Awọn ijọba ibilẹ ọhun, gẹgẹ bi kọmisanna feto iroyin, Funkẹ Ẹgbẹmọde, ṣe wi ni ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa, Iwọ-Oorun Ileṣa, Ila-Oorun Atakunmọsa ati Iwọ-Oorun Atakunmọsa

Ọjọ keje, oṣu yii, nigbele naa yoo bẹrẹ fun ọsẹ kan akọkọ, bi awọn eeyan naa ba si ṣe pa ofin to n dena itankalẹ arun naa mọ si ni yoo sọ boya ijọba yoo tun fi ọjọ le e tabi bẹẹ kọ.

Ẹgbẹmọde waa sọ pe igbesẹ naa nira fun ijọba lati gbe, ṣugbọn o di dandan lati dinwọ arun korona ku nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply