Ijọba ipinlẹ Ọṣun pohun da, o ni kawọn Kristiẹni ṣe isin aisun ọdun tuntun, ṣugbọn …

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lẹyin ọpọlọpọ ifikunlukun, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti fun awọn Onigbagbọ lanfaani lati ṣe isin aisun ọdun tuntun.

Ṣaaju nijọba ti kede pe ko gbọdọ si isin naa latari bi ọrọ ajakalẹ arun Koronafairọọsi ṣe n fẹ kaakiri bayii, ti iye awọn to n lugbadi rẹ si n pọ si i.

Latigba naa ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi, iyẹn CAN, ti n ṣepade pẹlu awọn alaṣẹ ijọba lati tun ero rẹ pa lori aṣẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Kọmisanna feto iroyin ati ilanilọyẹ, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita nijọba ti sọ pe ki wọn ṣe isin naa, ṣugbọn ẹnikẹni ko gbọdọ ju aago kan oru lọ nita.

O ni ki gbogbo isin tete pari, ki awọn ọmọ ijọ si ti wa ninu ile wọn titi aago kan oru, nitori oju arufin nijọba yoo fi wo ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ lẹyin aago kan oru ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.

Ijọba waa kilọ fun gbogbo awọn pasitọ lati ri i pe awọn ọmọ ijọ wọn tẹle ilana tijọba gbe kalẹ lori idena arun korona.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, latọjọ ti mo ti ṣojọọbi mi ni itẹkuu lawọn oku ti n yọ mi lẹnu

Monisọla Saka Kayeefi! Inu iboji larakunrin yii ti ṣe ọjọ ibi ẹ. Oṣerekunrin ilẹ Ghana …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: