Ijọba ipinlẹ Ọyọ sun ọjọ idanwo aṣewọle sileewe girama siwaju

Nitori bi ọjọ ti wọn fẹẹ ṣe idanwo aṣewọle sileewe girama nipinlẹ Ọyọ ṣe papọ mọ asiko ti wọn n ṣedanwo ileewe girama, (WAEC), ijọba ipinlẹ naa ti sun ọjọ idanwo yii si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, dipo ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejọ, ọdun yii, to yẹ ko waye.

Lọjọ Isegun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Komiṣanana fun eto Ẹkọ, Sayẹnsi ati Imọ ẹrọ, Ọlasunkanmi Ọlalẹyẹ, kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi sita. O ṣalaye pe idanwo aṣewọle sileewe girama yii ko ni i waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu yii, ti wọn fi si tẹlẹ nitori bo ṣe papọ mọ ọjọ ti wọn maa ṣe idanwo Iṣẹ Ọgbin (Agriculture) ati ẹkọ nipa Ọrọ Aje ( Economics) awọn oniwee mẹwaa to n lọ lọwọ. Idi niyi to ni awọn fi sun un si ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an yii.

O rọ gbogbo awọn obi lati ṣakiyesi eleyii, ki wọn si ri i pe wọn mu awọn ọmọ wọn lọ fun idanwo naa ni ọjọ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ mu. Bẹẹ lo gba wọn niyanju lati tẹle ofin ati ilana ti ijọba gbe kalẹ lori ọrọ Koronafairọọsi.

Leave a Reply