Ijọba kede adinku owo data, o lawọn ileeṣẹ ẹrọ ibanisọrọ gbọdọ tẹle e

Dada Ajikanje

Ọ jọ pe iroyin ayọ yii yoo ṣe ọpọ awọn ọmọ Naijiria loore, paapaa awọn to fẹran lati maa lo ikanni ayelujara daadaa.

Ni bayii, ijọba apapọ ti ṣadinku iye owo tawọn eeyan yoo fi maa ra data sori ẹrọ foonu wọn. Iko aadọta gan-an ni adinku tijọba ti paṣe pe ki wọn ṣe si iye ti wọn n ra data naa bayii. Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, gan-an ni wọn kede eyi.

Bakan naa ni ijọba ti pa ajọ to n ṣamojuto eto ibanisọrọ, iyẹn Nigerian Communications Commission, laṣe lati ri i pe igbesẹ waye lori aṣẹ tuntun ọhun, ki awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibanisọrọ si tẹle e.

Pẹlu igbesẹ tuntun yii, data ti awọn eeyan n ra ni ẹgbẹrun kan naira yoo di irinwo naira ati naira mẹtadindinlaaadọrun-un (487) fun data giigi kan (1GB), bẹẹ nijọba sọ pe latinu oṣu kọkanla to kọja yii lo yẹ ko ti bẹrẹ.

Minisita fun eto ibanisọrọ ati okoowo ẹrọ igbalode, Dokita Isa Ibrahim Pantami, lo kede ọrọ yii, bẹẹ lo sọ pe igbesẹ ọhun waye pẹlu ilana tijọba gbe kalẹ fun ajọ to n ṣakoso eto lilo ẹrọ ibanisọrọ.

Patanmi sọ pe, “Iye ti wọn n ra data 1GB laarin oṣu kin-in-ni, ọdun yii, si ọsu kọkanla, ti kuro ni ẹgbẹrun kan naira, o ti di irinwo naira ati naira mẹtadindinlaaadọrun-un (487).

O fi kun un pe lara igbesẹ ajọ ọhun ni lati fun araalu lanfaani lati maa ra giigi data kan ni naira mọkandinnirinwo (N390) nigba ti yoo ba fi di ọdun 2025.

Bakan naa ni ileeṣẹ yii ti ṣeleri fawọn eeyan orilẹ-ede yii pe eto ati ilana ti wa lati ri i daju pe awọn ileeṣẹ ẹlẹrọ ibanisọrọ tẹle aṣẹ ijọba lai yan araalu jẹ rara.

 

Leave a Reply