Ijọba kede ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọruu gẹgẹ bii ọlude ọdun Ileya

Faith Adebọla

Ijọba apapọ ti kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, ati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ jake-jado orileede yii, lati sami ayẹyẹ ọdun Ileya, Eid-el-Kabir tọdun yii.

Atẹjade kan ti Akọwe agba nileeṣẹ to n mojuto ọrọ abẹle, Dokita Shuaib Belgore, fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lorukọ Minisita ileeṣẹ ọhun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, sọ pe ijọba apapọ ba gbogbo awọn ẹlẹsin Musulumi orileede yii ati lẹyin odi yọ pe oju wọn tun ri ọdun Ileya to wọle yii.

Atẹjade naa gba wọn nimọran lati ṣọdun jẹẹjẹ, ki wọn si ranti ẹmi ifẹ, iṣọkan, alaafia ati ifara-ẹni-rubọ ti ojiṣẹ nla, Mohammed, ṣapẹẹrẹ rẹ, pe ki wọn si ṣamulo rẹ.

“A tun fẹẹ kẹ ẹ lo akoko yii lati gbadura fun alaafia, iṣọkan ati aasiki fun orileede Naijiria, paapaa pẹlu bi a ṣe n koju ipenija eto aabo lasiko yii, tawọn agbebọn ati afẹmiṣofo n ṣọṣẹ kaakiri agbegbe Ariwa, tawọn adigunjale, awọn ajijagbara ati awọn ajijigbe si ba awọn agbegbe yooku finra kaakiri.”

Minisita naa tun sin awọn araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki wọn ṣọra gidi bi wọn ṣe n ṣe pọpọ-ṣinṣin ọdun kaakiri, ki wọn si ri i daju pe eto aabo gidi wa fawọn ọmọ wọn, tori awọn ọmọde ti di afojusun fawọn ajinigbe lati fi maa pawo.

Bakan naa lo ran wọn leti pe ofin to rọ mọ arun koronafairọọsi to tun fẹẹ gberi lorileede yii, nipa lilo ibomu, oogun apakokoro, yiyẹra fun ikorajọ ero, ati awọn alakalẹ mi-in.

O ni ijọba Muhamadu Buhari ko ni i fọwọ lẹran lori ọrọ aabo yii, o lawọn n laagun gidi lori ẹ.

Leave a Reply