Faith Adebọla
Ijọba apapọ ti kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2021, gẹgẹ bii ọjọ iṣinmi lẹnu iṣẹ jake-jado orileede yii.
Atẹjade kan lati ọfiisi Minisita ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, eyi ti wọn fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee yii, l’Abuja, sọ pe isinmi naa jẹ lati sami ayẹyẹ ọjọọbi Anọbi Muhammad, eyi tawọn Musulumi maa n pe ni Eid-ul-Mawlid.
Atẹjade ọhun, ti Akọwe agba ileeṣẹ ọrọ abẹle, Dokita Shuaib Belgore, buwọ lu lorukọ minisita wọn, gba awọn ọmọ Naijiria niyanju lati lo anfaani isinmi naa fun igbelarugẹ ẹmi ifẹ, iṣọkan, alaafia ati ifarada, eyi to wa lara awọn nnkan amuyẹ ti Anọbi Muhammad waasu rẹ nigba to wa laye.
Arẹgbẹṣọla rọ awọn Musulumi lati yẹra fun iwa janduku ati iwa ọdaran eyikeyii, ki wọn si fi ara wọn han gẹgẹ bii aṣoju ati ọmọ orileede Naijiria rere, o ni ipo pataki lorileede Naijiria wa laarin awọn ile ilẹ adulawọ yooku.
O tun rọ awọn ọmọ orileede yii lapapọ lati fọwọ sowọ pọ pẹlu iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari lẹnu ilakaka rẹ lati wa ojutuu si awọn iṣoro to n ba orileede Naijiria finra, ki orileede naa le tubọ goke agba bo ṣe yẹ.