Ijọba apapọ ti kede Ọjọbọ, Wẹsidee, ọjọ kejila, ati Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu yii, gẹgẹ bii ọlide lati sami ayẹyẹ ọdun Itunu aawẹ (Eid-el-Fitri).
Atejade kan lati ileese to n ri si oro abele lo fi eyi lede lojo Aje, Monde, ose yii pe ojo mejeeji yii wa fun awon elesin Musulumi lati fi sinmi leyin aawe osu kan ti won gba.
A ki gbogbo awọn ololufẹ ALAROYE ati AKEDE AGBAYE pe Ọlọrun yoo fun wọn ni ẹsan aawẹ.