Ijọba kilọ faraalu ni Kwara, nitori arun korona to tun pa eeyan kan

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ijọba Kwara ti ṣekilọ fawọn araalu lati maa kiyesara, ki wọn si tẹsiwaju ninu pipa awọn ofin Covid-19 mọ nipa yiyago fun ikorajọ ati bẹẹ lọ, nitori pe arun korona ṣi wa kaakiri.

Alukoro igbimọ Covid-19 nipinlẹ Kwara to tun jẹ akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, lo gbe ikilọ naa sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹyin ti ọkan lara awọn alarun korona ku laaarọ ọjọ naa.

Ni bayii iye awọn ti arun naa ti pa nipinlẹ Kwara ti wọ ọgbọn, awọn mi-in ṣi wa nibudo tijọba ya sọtọ fun itọju Covid-19.

Ijọba ni bi arun naa ba tun burẹkẹ latari iwa aibikita awọn araalu, o le di ohun tapa ko ni i ka mọ.

Ajakaye ni, “ijọba rọ gbogbo araalu lati yago fun ibi ti ero ba pọ si, ki wọn maa lo ibomu, ki wọn si maa fọwọ wọn loorekore pẹlu ọsẹ.

“Pẹlu bi a ti ṣe n wọ asiko ọdun, a bẹ araalu lati mọ pe arun Covid-19 ṣi n ja kaakiri, koda, o wa nipinlẹ Kwara. A gbọdọ jinna si ohun to le mu ki kinni ọhun burẹkẹ.”

Akọsilẹ ajọ to n gbogun ti arun lorilẹ-ede, NCDC, fi han pe ẹgbẹrun kan le ọgọrun-un kan ati mejila, 1,112, lo ti lugbadi arun naa nipinlẹ Kwara, lara wọn, ẹgbẹrun kan ati mẹrinlelaaadọta lara wọn ti da ṣaka.

Leave a Reply