Eeyan mẹfa ku, ọwọ tẹ mọkadinlogun, nibi ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Dalemọ ati Alakukọ

Kazeem Aderounmu

O kere tan, ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkandinlogun lọwọ awọn agbofinro tẹ lagbegbe Alakukọ, niluu Eko lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ninu alaye ti awọn ẹṣọ agbofinro ṣe ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti fi awọn eeyan ọhun sọwọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti, Yaba, l’Ekoo.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa nipinlẹ Eko, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, fi kun un pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti fẹnu abuku kan wahala ti awọn janduku ọmọ ẹgbẹ okunkun n da silẹ lagbegbe Alakukọ, Dalemọ, l’Ekoo.”

Ni bayii, ọmọ ẹgbẹ okunkun mọkandinlogun lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ nibi ti wọn ti n bara wọn ja. Bakan naa ni Adejọbi ni oriṣiiriṣii ohun ijanba oloro ni wọn ba lọwọ wọn ati igbo paapaa.

O fi kun un pe kọmiṣanna ọlọpaa ti fidi ẹ mulẹ pe agbegbe Ọta, nipinlẹ Ogun, lawọn janduku ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ti waa ṣoro ki ọwọ awọn ọlọpaa too tẹ wọn.

Ni bayii, wọn lo ti le ni eeyan mẹfa ti wọn ti padanu ẹmi wọn ninu wahala awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n ṣẹlẹ lagbegbe Dalemọ ati Alakukọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja, ni wọn sọ pe wahala ọhun bẹrẹ, ti wọn si lo anfaani ija buruku ti wọn n ja yii fi ja araalu lole.

Ọkunrin kan ti wọn pe ni Biọdun Confidence, ni wọn pe ni olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun adugbo Dalemọ, nipinlẹ Ogun ọhun, nigba ti tawọn Alakukọ n jẹ Ori Tiles Boys. Igun ori awo ti wọn maa n lẹ mọ ile, iyẹn tiles, ni wọn sọ pe awọn ti Alakukọ fi n ja, ti wọn tun maa n fi i ṣiṣẹ ibi lati ja araalu lole lasiko ija wọn. Wọn ni bi wọn ṣe n ja ṣọọbu ni wọn n kole onile, ti wọn si n ṣe araalu leṣe pẹlu.

Gbogbo awọn to n taja laduugbo Alakukọ ni wọn ki i le patẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ba ti bẹrẹ wahala wọn.

Ṣiwaju si i, Ọmọọba Adejọbi sọ pe kọmiṣanna ọlọpaa ti kilọ fawọn ọlọkada, awọn onimọto akero ati gbogbo eeyan ipinlẹ naa lapapọ lati bọwọ fun ofin ti wọn ko ba fẹẹ ri pipọn oju ijọba.

Bẹẹ lo ni ofin ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ẹnikẹni to ba ṣiwọ lu ọlọpaa tabi eyikeyii ẹṣọ agbofinro, tabi ti wọn ba mu ẹnikẹni pe ko pa ofin igbogun-ti itankalẹ arun Koronafairọọsi mọ.

 

Leave a Reply