Ijọba ko ẹṣọ alaabo lọ sibi tawọn agbebọn ti paayan meji ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ijọba ipinlẹ Kwarati paṣẹ pe ki wọn ko awọn ẹṣọ alaabo lọpọ yanturu lọ si agbegbe Obbo Aiyegunle/Osi, ni Iha Guusu ipinlẹ Kwara, nibi ti awọn agbebọn ti da awọn arinrin-ajo lọna, ti wọn pa eeyan meji ninu wọn, ti wọn si tun ji awọn mẹwaa gbe lọ, ki wọn le wa awọn agbebọn naa lawari ti obinrin n wa nnkan ọbẹ.
Gomina Abdulrazaq ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si awọn olugbe Obbo Aiyegunle, lori iṣẹlẹ buruku ọhun, o ni ki wọn fọwọ wọnu lori awọn eeyan wọn ti awọn agbebọn ji gbe lọ, tori pe ijọba ti ko awọn ẹṣọ alaabo bii awọn ọmọ ogun ori ilẹ, ẹṣọ alaabo ọtẹlẹmuyẹ, ọlọpaa atawọn fijilante lọ si agbegbe naa bayii fun eto aabo to gbopọn, ti wọn yoo si doola awọn eeyan wọn kuro lọwọ awọn ajinigbe naa.
Kọmisanna lẹka ibanisọrọ nipinlẹ Kwara, Bọde Towoju, sọ pe ijọba kẹdun pẹlu mọlẹbi eeyan meji ti wọn pa, ati pe ijọba yoo sa gbogbo ipa rẹ lati doola ẹmi awọn mẹwaa to wa lakata awọn ajinigbe, ti wọn wọn yoo si fi awọn olubi eeyan naa jofin bi ọwọ ba tẹ wọn, tori pe ẹlẹsẹ kan ko ni lọ lai jiya.

Leave a Reply