Ijọba ko ni i kede ofin konile-gbele nitori arun Koronafairọọsi- Lai Muhammed

Ijọba apapọ ti sọ pe oun ko ṣetan lati kede ofin konile-gbele lori bi arun Koronafairọọsi ṣe tun bẹrẹ si ni gbilẹ si i bayii.

Minisita fun eto iroyin, Alhaji Lai Mohammed, lo sọrọ yii lọjọ Iọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lasiko to n sọrọ lori eto kan lori redio.

Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe ijọba apapọ ko ti i kede pe ki awọn eeyan jokoo sile pẹlu bii arun Koronafairọọsi tun ṣe n burẹkẹ si i bayii. O ni bii ẹni pe awọn ileeṣẹ iroyin ti wọn gbe ọrọ ọhun ṣi ajọ ti Aarẹ gbe kalẹ lati maa mojuto itakanlẹ arun ọhun gbọ ni lasiko ti wọn n ṣalaye bi arun ọhun ti ṣe tun bẹrẹ si gbilẹ si i lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii.

Lai Mohammed sọ pe idaamu nla ni igbesẹ ọhun yoo tubọ ko ba ọrọ aje to ti dẹnukọlẹ tẹlẹ ti ijọba ba tun se awọn eeyan mọle lẹẹkan si i.

O fi kun un pe ohun ti ijọba apapọ n gbiyanju lati ṣe bayii ni bi awọn eeyan ko ṣe ni i maa kora wọn jọ lọpọ yanturu soju kan, ati pe eyi gan-an naa lo mu ijọba paṣe pe ki awọn oṣiṣẹ ijọba lati ipele kejila si isalẹ maa ṣiṣẹ lati ile wọn.

Bakan naa nijọba ti sọ pe ko gbọdọ si ayẹyẹ oru, awọn ofin to de itankalẹ arun Koronafairọọsi yii tẹlẹ si ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pada bayii.

Wọn ti ni ko ni i si ikojọpọ ni ṣọọṣi ati mọṣalaṣi mọ, ati pe awọn aririn-ajo paapaa gbọdọ ni iwe ẹri ti wọn yoo fi han pe wọn ko ni arun ọhun ki wọn too le wọle si Naijiria.

Bẹẹ gẹgẹ lawọn to ba wọle yoo fi ara wọn pamọ fun ọjọ meje, lẹyin naa ni wọn yoo tun ṣayẹwo pe ṣaka lara awọn da. O ni gbogbo igbesẹ yii waye lati fi dena itakanlẹ arun ọhun ni.

Tẹ o ba gbagbe, lati dawọ itakanlẹ arun ọhun duro lo mu ijọba ipinlẹ Eko paṣẹ ki awọn oṣiṣẹ ẹ lati ipele kẹrinla si isalẹ maa ṣiṣẹ wọn latile, bẹẹ gẹgẹ ni ijọba Kaduna naa ṣe.

 

Leave a Reply