Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, paṣẹ pe ki wọn da ilee-kowe-pamọ-si to jẹ ti Olushọla Saraki ti i ṣe baba adari ile aṣofin agba tẹlẹ nilẹ yii, Bukọla Saraki, eyi to wa ni agbegbe Agbo-ọba, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun (West) Ilọrin, ipinlẹ Kwara wo. Ko sẹni to mọ idi pataki ti wọn fi da a wo, ṣugbọn ọsan gangan ni katakata bẹrẹ si i da ile ọhun wo.