Ijọba Kwara pin miliọnu mọkanlelọgbọn fawọn to fara gba ninu ijamba epo bẹntiroolu ni Jẹbba

Stephen Ajagbe, ilorin

Ijọba ipinlẹ Kwara, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, bẹrẹ pinpin miliọnu mọkanlelọgbọn naira to jẹ owo iranwọ fawọn araalu to din diẹ ni igba ti wọn fara pa tabi padanu dukia wọn nibi ijamba ina tanka epo bẹntiroolu to ṣẹlẹ loṣu kejila, ọdun 2020, niluu Jẹbba, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara.
Ṣaaju akoko yii ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ti ṣabẹwo si wọn, to si fun wọn lẹbun owo lati ran wọn lọwọ.
Akọwe iroyin gomina, Rafiu Ajakaye, ni eeyan ọgọrun-un kan ati mẹrinlelaaadọrun, 194, lo maa jẹ anfaani owo naa. O ni o kere ju ẹni kan maa gba laarin ẹgbẹrun ọgbọn naira si miliọnu kan.

O ni awọn tile wọn jọna maa gba owo to bẹrẹ lati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹjọ naira si miliọnu kan. Mọlẹbi awọn to padanu eeyan wọn ninu ijamba ina naa maa gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un mẹta naira.
Ọnarebu John Bello to ṣoju ijọba nibi eto pinpin owo naa rọ awọn to janfaani ẹ lati lo o daadaa.
Ẹni kan to gbẹnu sọ fawọn to jẹ anfaani owo naa, Ọnarebu John Okedare, gboriyin fun Gomina fun bo ṣe bẹ awọn eeyan naa wo ati eto iranlọwọ to ṣe fun wọn.

Leave a Reply