Ijọba Kwara ra awọn ọkọ agbalaisan lati gbogun ti arun korona

Stephen Ajagbe, Ilọrin

Lara igbesẹ ijọba lati gbogun ti arun aṣekupani Koronafairọọsi lo mu ki Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ra awọn ọkọ to n gbe alaisan tuntun meji, to ni gbogbo ohun eelo itọju iṣẹlẹ pajawiri, ICU, ninu.

Nigba to n yẹ awọn ọkọ mẹsidiiisi naa wo lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, gomina gboriyin fawọn oṣiṣẹ ilera fun ipa ti wọn n ko lori igbogun ti arun Korona ni Kwara.

O ni ni igbesẹ naa jẹ ọkan lara ipa tijọba oun n ko lati pese eto ilera to dangajia fun araalu.

O rọ ileeṣẹ to n mojuto eto ilera lati ṣe amulo awọn ọkọ atawọn ohun eelo to wa ninu wọn daadaa, pẹlu ileri pe ijọba yoo tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fun ẹka naa.

Kọmiṣanna feto ilera, Dokita Raji Razaq, gboṣuba fun gomina pẹlu ipese awọn irinṣẹ ati atilẹyin to n ṣe fawọn oṣiṣẹ ilera.

Leave a Reply