Ijọba lawọn o fowo kun owo epo, wọn tọrọ aforiji lọwọ araalu

Faith Adebọla

 

 

Pẹlu bi aroye ati ariwo ṣe gba igboro kan lẹyin ti ajọ to n ri si ẹkunwo ati adinku owo-epo rọbi atawọn eroja nilẹ wa (Petroleum Products Pricing Agency, PPPRA) sọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee yii, pe awọn ti sun owo tawọn araalu maa maa ra lita epo bẹntiroolu kan si igba ati mejila naira (#212.60), ijọba apapọ ti sọ pe awọn o fọwọ si ẹkunwo naa, wọn si tọrọ aforiji lọwọ araalu. Naira mẹrin din lọgọsan-an (#176) lọpọ ileepo n ta epo naa tẹlẹ.

Minisita fọrọ epo rọbi nilẹ wa, Timipre Sylva, lo kede lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, pe oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari ko mọ ohunkohun nipa ẹkunwo ti wọn kede naa, bẹẹ lawọn o fọwọ si i.

Bakan naa ni ajọ to n bojuto igboke-gbodo epo rọbi, Nigerian National Petroleum Corporation, NNPC, sọ pe ko si idi lati fowo kun owo-epo lọwọ yii, wọn niye tawọn ileepo n ta epo tẹlẹ ni ki wọn ṣi maa ta a, ko si pẹ ti ajọ NNPC ṣe kede ọrọ yii tan ni ajọ PPPRA lọọ pa ikede ẹkunwo ti wọn lawọn ṣe naa rẹ lori ikanni wọn.

Timipre Sylva sọ pe “ijọba o le maa purọ faraalu, ikede ti wọn ṣe lati fi kun owo epo yii ko lọwọ ijọba ninu, ko si si ootọ ninu ọrọ naa.

“A mọ pe ikede ti wọn ṣe yii ti maa ko yin lọkan soke, o si ti maa fa aifararọ fawọn kan. A tọrọ aforiji fun ọrọ to ṣẹlẹ yii, a o fi kun owo epo o, ẹ jọọ, ẹ ma binu”, awọn ọrọ ẹbẹ yii ni minisita naa fi kadii ikede rẹ.

Leave a Reply