Ijọba lawọn yoo ṣi awọn ẹnubode ilẹ wa laipẹ

Nibi ipade idakọnkọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe pẹlu awọn goimina to wa ni gbogbo ipinlẹ mẹrindinlogoji nilẹ wa, niluu Abuja, lo ti sọ pe ki awọn le dẹkun fayawọ ati kiko ohun eelo ijagun ati awọn oogun loriṣiiriṣii lawọn fi ti awọn ẹnubode ilẹ wa pa.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ Aarẹ fi sita lori ipade naa ni wọn ti rọ awọn gomina lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba alaye lati le mọ awọn ohun to n lọ lagbegbe wọn.

Agbẹnusọ Aarẹ lori eto iroyin, Sheu Garba, sọ lorukọ Aarẹ Buhari pe ijọba ko ni i pẹẹ ṣi ẹnuubode ti wọn ti pa.

Nigba to n sọrọ lori abọ awọn gomina lori eto aabo kaakiri agbegbe wọn. Bẹẹ ni Buhari sọ pe ijọba oun ti ṣe daadaa lori eto aabo, paapaa ju lọ ni Ila Oorun Ariwa (North East) ati Guusu Guusu (South South), ṣugbọn wahala ṣi wa ni iha Guusu Guusu yii.

Aarẹ Buhari ni eto aabo ṣẹ pataki, a si gbọdọ daabo bo ilẹ wa lọwọ awọn ajinigbe ati janduku. O ni awọn yoo ṣe atilẹyin fun ileeṣẹ ologun lati le ri awọn janduku atawọn ajinigbe yii mu, ati lati fopin si wọn patapata.

Wọn ka ẹya ara eeyan mọ tẹgbọn-taburo lọwọ niluu Iwo, lawọn ọdọ ba dana sun ile wọn

 

Leave a Reply