Ijọba lo ti deewọ lati gbe ọmọbinrin tọjọ ori rẹ ko to ọdun mejidinlogun lọ s’otẹẹli

Ijba lo ti deew lati gbe ọmọbinrin tj ori r ko to dun mejidinlogun l sotẹẹli

Adewale Adeoye

Minisita fun ọrọ obinrin lorileede yii, Abilekẹ Uju Kennedy Ohaneye, ti sọ pe ijọba  orileede yii ko ni i fojuure wo awọn ọbayejẹ gbogbo ti wọn n gbe awọn ọmọdebinrin tọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọ s’otẹẹli kaakiri orileede yii mọ. O ni iya nla nijọba maa fi jẹ ẹni yoowu tọwọ ba tẹ pe o ṣe iru nnkan bẹẹ lawujọ wa bayii. Ọjọ Abameta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lo sọrọ ọhun di mimọ nibi eto pataki kan to waye niluu Abuja.

ALAROYE gbọ pe lara ọna tijọba fẹẹ gba lati din bi awọn oniṣẹ ibi ṣe n ko awọn ọmọde tọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọọ fi ṣowo ẹru l’Oke-Okun, ni wọn ṣe ṣofin naa sita bayii.

Aipẹ yii ni fidio kan jade sita, nibi ti aworan awọn ọmọde kan lati ilẹ wa ti wọn ko  lọọ ṣowo ẹru lorileede Ghana ti jade, ti ọjọ ori awọn ọmọ naa ko ju ọdun mẹẹẹdogun si mẹrindinlogun lọ.

Ninu ọrọ rẹ lo ti ni, ‘’O ti deewọ fawọn eeyan lorileede yii lati mu ọmọdebinrin tọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọ si otẹẹli bayii, ijiya nla lo wa fẹni to ba ṣe bẹẹ. Bẹrẹ lati ogunjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, a ti pa a laṣẹ fawọn otẹẹli igbalode gbogbo pe ki wọn gbe patako ipolongo sita pe awọn ko gba pe ki wọn gbe ọmọ t’ọjọ ori rẹ ko to ọdun mejidinlogun wa sọdọ wọn mọ. Ọwọ lile la maa fi mu ọrọ naa bayii, kekere ni ijiya tawọn kan jẹ nipinlẹ Niger, lori iru ọrọ naa, bi erin ba dan an wo bayii, iwo rẹ aa lọ ni. A ko ni i faaye gba iwa palapala mọ laarin ilu, ko yẹ ki won maa gbe awọn ọmọ t’ọjọ ori wọn ko to ọdun mejidinlogun lọ si otẹẹli mọ.

Leave a Reply