Ijọba Makinde ṣefilọlẹ ọja Akẹsan tuntun niluu Ọyọ

Tilu-tifọn ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi ṣefilọlẹ Ọja Akẹsan tuntun, niluu Ọyọ, eyi tijọba fẹẹ berẹ atunkọ rẹ lẹyin ti ọja naa jona lọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni, ọdun to kọja.

Ileri ijọba bayii ni pe awọn yoo sọ ọja naa di ti igbalode, ti yoo si ni awọn ohun amayedẹrun loriṣiiriṣii ti yoo dena iru wahala to ṣẹlẹ ninu ọja naa lọdun to kọja.

Gomina Makinde ṣalaye pe awọn waa mu ileri awọn lati kọ ọja naa ṣẹ lẹyin tawọn pese owo iranlọwọ fun awọn ọlọja to lugbadi ijamba ina naa gẹgẹ bi agbara ijọba ṣe mọ.

Gẹgẹ bii eto ti ijọba gbe kalẹ, awọn sọọbu nla to le ni ẹẹdẹgbẹta (520) nijọba yoo kọ sibe, nigba ti awọn isọ bii mejidinlasaadọsan-an yoo wa nibẹ pẹlu. Bakan naa ni ọja yii yoo ni ile-ẹja, agọ ọlọpaa, omi ẹrọ, ileewosan ati bẹẹ bẹẹ lọ. O fi kun un pe pe ẹrọ omi ati awọn nnkan eelo to le pana loju ẹsẹ yoo wa nibẹ lati dena ki ina tun jo ọja yii lọjọ iwaju.

O fi kun un pe agbaṣẹṣe kan lati ilu Ọyọ, MORTAYUS NIGERIA LIMITED, ni yoo ṣiṣẹ naa, wọn si ti ṣeleri pe awọn yoo pari iṣẹ lori ọja yii laarin ọdun kan, eyi ti yoo fi di lilo fun awọn araalu. Niṣe ni inu awọn iyalọja n dun sinkin, ti wọn si n gbadura pe ki Ọlọrun ran ijọba ati awọn agbaṣẹṣe lọwọ ki ọja naa le tete pari fun lilo.

Igbakeji Gomina Ọyọ, Ẹnjinnia, Rafiu Ọlaniyan, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi atawọn alaṣẹ ijọba lo peju sibi ifilọlẹ ọhun.

One thought on “Ijọba Makinde ṣefilọlẹ ọja Akẹsan tuntun niluu Ọyọ

Leave a Reply