Ijọba Naijiria n ha dọla fawọn eeyan dudu l’Amẹrika, ki wọn le ṣewọde tako wa lọdọ Ajọ Iṣọkan Agbaye – Banji Akintoye

Faith Adebọla

Alaga ẹgbẹ NINAS, iyẹn ẹgbẹ awọn to fẹẹ ya kuro lara Naijiria, Ọjọgbọn Banji Akintoye, ti tu aṣiiri pe niṣe nijọba Naijiria n hawo bii ẹlẹda l’Amẹrika bayii, wọn n fowo naa haaya awọn eeyan dudu l’Amẹrika pe ki wọn ba awọn ṣewọde tako iwọde ti ẹgbẹ NINAS fẹẹ ṣe aṣekagbara rẹ lolu-ileeṣẹ Ajọ Iṣọkan Agbaye lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Ọjọgbọn Akintoye sọrọ yii ninu atẹjade kan ti Akọwe ẹgbẹ NINAS to tun jẹ agbẹnusọ baba naa, Ọgbẹni Maxwell Adelẹyẹ, fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, lori bi nnkan ṣe n lọ si lorileede Amẹrika ti wọn ti n ṣe iwọde lọwọ.

Wọn ni inu ibẹrubojo ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati ikọ to ko sodi wa si apero agbaye naa wa, paapaa bi ireti ṣe wa pe Aarẹ yoo ba awọn ijokoo awọn olori orileede agbaye naa sọrọ lọjọ Ẹti, bẹẹ ọjọ naa ni ẹgbẹ NINAS fẹẹ ṣe aṣekagba iwọde wọn, ti wọn ti ṣeto pe miliọnu kan eeyan lo maa yan bii ologun, ti wọn yoo si ṣe iwọde wọọrọwọ yika agbala ile naa.

Ṣe lati ọjọ kẹrinla ni iwọde naa ti n waye nile ẹgbẹ naa, tawọn oluwọde naa n fi erongba wọn han, ti wọn si n parọwa si Ajọ Iṣọkan Agbaye to n ṣepade kẹrindinlọgọrin wọn lọwọ pe ki wọn ba awọn da si ọrọ Naijiria, ki wọn si ṣatilẹyin fun yiya kuro tawọn gun le ọhun.

Ọjọgbọn Akintoye ni niṣe lara n fu ikọ tijọba Naijiria ko wa naa, wọn ni afaimọ ni aṣekagba iwọde ti ẹgbẹ NINAS fẹẹ ṣe ọhun ko ni i mu itiju ati abuku dani fun Aarẹ Buhari lasiko ti yoo maa ba awọn Ajọ Agbaye naa sọrọ, idi eyi ni wọn ṣe n nawo nara lati haaya awọn eeyan ti yoo ṣe iwọde mi-in tako NINAS ti wọn yoo si maa sọrọ rere nipa Aarẹ ati ijọba Naijiria.

“Lai ka bi awọn eeyan bii Kinniun yii ṣe n nawo bii ṣekẹrẹ si, ko sọna ti wọn fi maa bori kọlọkọlọ tiwa, tori a wa niṣọkan, abẹ ijọba dẹmokiresi la si wa.

Ọla ni aṣekagba iwọde naa maa waye niluu New York, l’Amẹrika, o si maa laami-laaka gidi, tori ẹ lẹru ṣe n ba ijọba Naijiria. Ọga agba kan nileeṣẹ ijọba Naijiria ati oniroyin kan lati ilu Eko ti wa l’Amẹrika bayii, awọn ni wọn n ṣe kukukẹkẹ kiri lati hawo fawọn eeyan dudu ti wọn ba ri, pe ki wọn le ba wọn ṣe iwọde tako wa, ẹẹdẹgbẹta owo dọla (500 USD) ni wọn ha fun wọn, ki wọn maa pariwo pe ijọba Buhari daa, ti Buhari lawọn fẹ.

Ṣugbọn mimi kan ko mi wa nitori iyẹn, a o tiẹ ri tiwọn ro rara. Ko si ajẹgaba le ni lori kan to le bori awọn eeyan ti wọn nipinnu. Awọn araalu lo ni ijọba, awọn ni wọn si ni agbara, tori eeyan lo ṣe iwe ofin orileede. Ọwọ araalu laṣẹ wa, ibẹ si lawa ti ri agbara tiwa, eeyan la fi bora bii aṣọ. Tori naa, iwọde wa maa jẹ fun anfaani awọn araalu, iwọde alaafia si ni bii tatẹyinwa.

A rọ gbogbo ẹyin eeyan wa ni Guusu ati Aarin-Gbungbun Amẹrika ati orileede Canada lati tu yaayaa jade lọpọ rẹpẹtẹ ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii, nileeṣẹ Ajọ United Nations, niluu New York, la ti maa ṣe iwọde wa, a fẹẹ taṣiiri niwaju agbaye pe ijọba-Fulani to wa lode yii ti ja ẹtọ ati aṣẹ araalu gba ni Naijiria, niṣe ni wọn n ṣe awa ati dukia wa yankanyankan nilẹ abinibi wa, ajọṣe wa ko rọgbọ, ko si le rọgbọ mọ, a fẹẹ maa lọ.” Bẹẹ latẹjade naa ka lapakan.

Leave a Reply