Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti paṣẹ pe ki awọn oṣiṣẹ ọba lati ipele kin-in-ni si ikejila pada sẹnu iṣẹ bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ yii.
Ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ni gomina paṣẹ bẹẹ ninu atẹjade kan ti Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Hakeem Muri-Okunọla, fi sita lorukọ gomina.
Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Lẹyin imọran ti a ti ri gba latọdọ igbimọ tijọba apapọ gbe kalẹ lori itankalẹ arun koronafairọọsi ati ẹka eto ilera ipinlẹ Eko, eyi ni lati kede pe gomina wa, Babajide Sanwo-Olu, ti fọwọ si i pe ki gbogbo oṣiṣẹ ọba lati ipele kin-in-ni si ikejila ta a ti ni ki wọn maa ti ile ṣiṣẹ wọn latinu oṣu kẹta, ọdun yii, pada ṣẹnu iṣẹ lọfiisi kaluku wọn, bẹrẹ lati ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun 2020.
“A ti ṣeto pe ki wọn kọ orukọ awọn oṣiṣẹ bi wọn ṣe n wọṣẹ laraarọ, ki wọn si ri i pe wọn pa ofin ati alakalẹ to yẹ lori idena arun korona mọ. Tẹ o ba gbagbe, kiki awọn oṣiṣẹ lati ipele kẹtala soke ni wọn n wa sibi iṣẹ ọba latari itankalẹ arun korona, nigba tawọn to ku lati ipele kejila sisalẹ n ṣiṣẹ lori ẹrọ ayelujara lati ile kaluku wọn.