Ijọba ni ko fun wa laṣẹ lati wọ’gbo lọọ ba awọn Fulani n’Ibarapa o – Amọtẹkun

Faith Adebọla

Pẹlu bi wahala ati iwa ọdaran awọn Fulani darandaran lagbegbe Ibarapa ṣe tun gbọna mi-in yọ lopin ọsẹ to kọja yii, tawọn Fulani darandaran tun lọọ yinbọn pa eeyan mẹrin loru mọju ọjọ Aje, Mọnde yii, labule Idiyan, lọna oko ilu Igangan si Ayetẹ, awọn ẹṣọ Amọtẹkun ti sọ pe ijọba ni ko fawọn laṣẹ lati wọ’gbo lọọ bawọn Fulani ti wọn ṣọṣẹ lagbegbe naa.

Igbakeji olori ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka tijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, Ọgbẹni Ishiau Adejare lo sọrọ yii nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lọjọ Aje, latari awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ lagbegbe naa.

Adejare ni loootọ lawọn Fulani kan tun lọọ paayan mẹrin loru mọju. O lawọn ti fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni teṣan wọn to wa l’Ayetẹ, wọn si ti lọ sibẹ, wọn ti ko oku awọn mẹrẹẹrin lọ si mọṣuari fun ayẹwo ati iṣẹ iwadii.

Nigba ta a beere idi tawọn ẹṣọ Amọtẹkun ko ṣe ti i lọọ pese aabo fawọn agbẹ lọna oko, Ishiawu ni ijọba ni o ti i fawọn laṣẹ lati ṣe bẹẹ ni.

“Ṣe ẹ mọ pe abẹ ijọba la wa, a o si le lọọ ṣiṣẹ kan nibi kan lai jẹ pe wọn ni ka lọ sibẹ. Aṣẹ ni o ti i wa latoke pe ka wọ’gbo lọọ pese aabo, tori ẹ lo fi jẹ pe aarin ilu ati sẹkiteria ijọba ibilẹ niṣẹ wa ṣi mọ bayii. Ti wọn ba ni ka lọ sibẹ, a maa lọ sibẹ, aijẹ bẹẹ, wọn le sọ pe niṣe la n da aṣẹ wa pa.

“Loootọ la gbọ pawọn Fulani kan lọọ ṣakọlu loru mọju oni labule Idiyan. Iyawo ọrẹ mi kan wa lara awọn ti wọn pa paapaa.

Bakan naa ni alukoro ẹgbẹ Igangan Desendants Association, Ọgbẹni Abiọdun Oguntowo, sọ pe adehun ti gomina ipinlẹ Ọyọ ṣe fawọn nigba to ṣabẹwo siluu Igangan kọ lo n ṣe yii. O lo kọ awọn lominu bawọn ikọ Amọtẹkun ṣe ta ku lati lọọ gbeja awọn agbẹ tawọn Fulani n ṣe ni ṣuta lọna oko wọn.

Leave a Reply