Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede imurasilẹ rẹ lati ṣe akọsilẹ iye awọn Fulani darandaran ti wọn n gbe nipinlẹ naa, ti wọn yoo si ka wọn lẹyọkọọkan.
Igbesẹ yii, gẹgẹ bijọba ṣe wi, ni yoo fi aaye silẹ lati mọ nipa awọn Fulani darandaran ti wọn n gbe ninu ilu kọọkan, ti yoo si jẹ ki alaafia ati irẹpọ le wa laarin awọn ẹya Fulani/Bororo atawọn Yoruba olohun ọgbin.
Lẹyin ipade alaafia ti awọn igbimọ to n ri si ibagbepọ alaafia laarin awọn Fulani/Bororo pẹlu awọn agbẹ ṣe pẹlu awọn adari ẹya Fulani ati Bororo ti wọn n pe ni Seriki, eleyii to waye ninu ọgba ileeṣẹ to n ri si ipese ounjẹ ati ọrọ ọgbin ni Abere, ni wọn ti fẹnuko bayii.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, alaga igbimọ naa, Ọnarebu Mudaṣiru Toogun, sọ pe o pọn dandan lati mọ, ati lati ni, akọsilẹ to peye lori awọn atọhunrinwa ti wọn n gbe ninu ipinlẹ Ọṣun.
Toogun ni eleyii yoo ran ijọba lọwọ lati le dena wahala to n fojoojumọ waye lori ọrọ eto aabo nipasẹ aikiyesi bi awọn eeyan ṣe n wọle nigba gbogbo.
O fi kun ọrọ rẹ pe akọsilẹ naa yoo ran ijọba lọwọ lati mọ awọn nnkan amayedẹrun ti wọn yoo pese fun lilo awọn Fulani ati Bororo ti wọn n gbe nipinlẹ Ọṣun.
Bakan naa lo gboṣuba fun awọn Seriki ọhun fun ifọwọsowọpọ wọn pẹlu ijọba Gomina Adegboyega Oyetọla, o si fi da wọn loju pe gomina ko ni i dẹkun wiwa alaafia laarin awọn agbẹ atawọn Fulani/Bororo.
Lati le ya epo kuro lara alikaama, Toogun sọ pe laipẹ nijọba yoo pin kaadi idanimọ fun gbogbo awọn Fulani darandaran atawọn Bororo, bẹẹ ni awọn agbofinro yoo maa duro wamuwamu lẹnuubode kọọkan lati maa kiyesi awọn ti wọn ba n wọle.
Ninu ọrọ rẹ, Seriki Fulani nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Ibrahim Babatunde, fi da ijọba loju pe awọn fara mọ gbogbo agbekalẹ ijọba lati le mu ki alaafia tubọ maa jọba laarin wọn atawọn agbẹ ẹya Yoruba.
O ni awọn eeyan oun yoo tubọ maa gbe lalaafia pẹlu awọn olugbe ilu kọọkan ti wọn wa, o si rọ ijọba lati tubọ maa ṣugbaa awọn loorekoore.