Ijọba Ọṣun kede konilegbele

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati aago mejila alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ko si ẹnikẹni to lanfaani lati rin kaakiri nipinlẹ Oṣun latari bijọba ṣe kede konilegbele, eleyii ti ko ni ọjọ ti yoo wa sopin.

Akọwe ijọba, Ọmọọba Wọle Oyebamiji, lo kede pe igbesẹ naa ṣe pataki lati le dena ojo wahala to n ṣu jọ pẹlu bi awọn janduku ṣe ti gbakoso ifẹhonu han EndSars.

O ni awọn ti iṣẹ wọn ṣe pataki, ti wọn si ni iwe idanimọ lọwọ nikan ni wọn yoo lanfaani lati lọ kaakiri.

Leave a Reply