Ijọba o gbọdọ fun ẹnikẹni labẹrẹ ajẹsara Korona ni tipatipa-Ile-ẹjọ lo sọ bẹẹ

Faith Adebọla

Ile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Port-Harcourt, nipinlẹ Rivers, ti sọ pe ọrọ gbigba abẹrẹ ajẹsara arun Koronafairọọsi ni Naijiria, ẹni to ba fẹ, to si nifẹẹ si gbigba abẹrẹ naa lo le lọọ gba a, ki i ṣe ọrọ tulaasi, bẹẹ nijọba o gbọdọ fipa fun ẹnikẹni labẹrẹ ọhun.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, nile-ẹjọ naa gbe aṣẹ yii kalẹ ninu idajọ lori ẹjọ kan ti nọmba rẹ jẹ FHC/PH/FHR/266/2021, eyi ti Ọgbẹni Charlse Godwin fi pe ijọba ipinlẹ Edo, Gomina Ọbaseki, atawọn mẹrin mi-in lẹjọ si kootu naa.

Gomina Obaseki lo ti kọkọ paṣẹ laipẹ yii pe dandan ni ki gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Edo lọọ gba abẹrẹ ajẹsara Korona, aijẹ bẹẹ, ijọba le ma jẹ ki wọn ṣejọsin ni ṣọọṣi ati mọṣalaṣi, awọn banki ati awọn ile-ijọba, wọn si tun le padanu awọn anfaani ati ẹtọ kan lọdọ ijọba ti wọn o ba ṣe bẹẹ.

Ipinnu yii ni olupẹjọ naa lọ pẹjọ le lori, o ni kile-ẹjọ ba awọn da si i, boya ijọba laṣẹ lati sọ gbigba abẹrẹ arun Korona di kan-n-pa bẹẹ.

Ninu alaye rẹ, agbẹjọro olupẹjọ rọ ile-ẹjọ lati da ijọba lọwọ kọ na, ki wọn si faaye gba a pe kawọn oniroyin ati iwe iroyin gbe gbogbo bi ẹjọ naa ba ṣe lọ si sojutaye.

Adajọ Adamu Turaki Mohammed to bojuto ẹjọ yii sọ pe oun fọwọ si ẹbẹ olupẹjọ, o ni kijọba Edo ma ṣe mu ẹnikẹni nipa lati gba abẹrẹ ajẹsara Korona titi ti igbẹjọ yoo fi pari lori ẹjọ naa, o ni ẹnikẹni to ba nifẹẹ si i le lọọ gba a tabi kọyin si i.

Adajọ naa sun igbẹjọ to kan si ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Leave a Reply