Ijọba Ogun bẹrẹ abẹrẹ ajẹsara to n dena arun digbolugi lara aja

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Ẹgbẹrun mẹfa abẹrẹ ajẹsara to le dena arun digbolugi lara awọn aja kaakiri ipinlẹ Ogun, ni ijọba ipinlẹ yii pẹlu ileeṣẹ eto ọgbin ti gbe jade bayii lati maa fun awọn aja. Ki itankalẹ arun naa le dinku lasiko yii, ko si dohun igbagbe pata nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030.

 Kọmiṣanna eto ọgbin nipinlẹ Ogun, Ọmọwe Adeọla Ọdẹdina, lo sọ eyi di mimọ nibi eto ti wọn fi bẹrẹ fifun awọn aja labẹrẹ naa, eyi to waye nileewosan awọn ẹranko (Veterinary Hospital Complex), Ita-Ẹkọ, l’Abẹokuta.

Ọfẹ ni abẹrẹ ajẹsara naa fawọn aja tawọn eeyan n sin nipinlẹ Ogun. Ọmọwe Ọdẹdina sọ pe oun to na wọn ko ju ki wọn ṣaa ko awọn aja wọn wa lati gba abẹrẹ ti yoo dena arun digbolugi toyinbo n pe ni Rabies, lara aja wọn.

Arun yii buru to bẹẹ to jẹ bi aja digbolugi ba bu eeyan jẹ, onitọhun yoo ku lẹyin ọjọ diẹ ni. Ọpọlọ eeyan ni wọn ni arun yii maa n ba ja, niṣe ni yoo kọkọ bẹrẹ bii iba fun ẹni ti aja digbolugi ge jẹ naa, ti ori yoo maa fọ ọ, ti yoo si maa rẹ ẹ.

Nigba ti wọn yoo ba si fi wo o loju fọjọ diẹ lai si itọju gidi, iku ni yoo ja si fun iru ẹni bẹẹ.

Lati dena iru eyi ni Kọmiṣanna yii sọ pe o fa a ti ileeṣẹ eto ọgbin fi bẹrẹ eto abẹrẹ ajẹsara naa nipinlẹ Ogun, eyi to ni o fi han pe ki i ṣe ipese ounjẹ nikan lẹka yii duro fun, wọn tun n mojuto alaafia awọn ẹranko ati tawọn olowo wọn pẹlu.

O fi kun un pe gbogbo ijọba ibilẹ ogun (20) to wa nipinlẹ Ogun ni wọn yoo gbe abẹrẹ naa lọ fawọn olowo aja lati janfaani ẹ.

 

Leave a Reply