Ijọba Ogun fọwọ si iyansipo Adebajo gẹgẹ bii Orimọlusi  tuntun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Igbimọ to n ri si ọrọ ọba jijẹ nipinlẹ Ogun ti fọwọ si iyansipo Lawrence Jaiyeọba Adebajo gẹgẹ bii Orimọlusi Ijẹbu-Igbo tuntun, bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, ọdun 2022.

  Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni  Adesọji  Adewuyi, adari ọrọ to ba jẹ mọ oye jijẹ nipinlẹ yii fọwọ si lo ti ki Orimọlusi tuntun yii ku oriire. Wọn tọrọ ẹmi gigun fun un pẹlu alaafia ara. Wọn si gbadura pe ki igba rẹ tu ilu Ijẹbu-Igbo lapapọ lara.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun kẹtadinlọgbọn ree ti ko ti si ọba n’Ijẹbu-Igbo, igbaradi si ti bẹrẹ bayii pẹlu imurasilẹ gidi lori bi ayẹyẹ ọba jijẹ naa yoo ṣe dun, ti yoo larinrin.

Idile ọba ni Orimọlusi tuntun yii ti wa, iyẹn ile Ojuromi, lati Oke Tako, n’Ijẹbu-Igbo. Ọmọọba  Tanimọwo Adebajo ni baba rẹ, iya rẹ si ni Safuratu Adebajo, ọmọ  Aderibigbe/ J.B. King, ni Atikori.

Ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 1953, ni wọn bi Lawrence Jaiyeọba ni Fowoseje, abule kan n’Ijẹbu-Igbo.

Ọba tuntun yii kawe, o ṣiṣẹ mọto titi to fi dẹni to ni mọto tara tiẹ to fi n pawo, o si pada dẹni to n nileeṣẹ mọto. Ko too pe ogoji ọdun, Jaiyeọba ti kọ awọn ile tiẹ si Aledo Oke, Agbo Ijẹbu Igbo, ati Ọkọta, niluu Eko.

Abilekọ Bọlanle Mary Adebajo niyawo rẹ, oniṣowo pataki lobinrin naa, ọmọ Osan-Ekiti ni. Wọn bimọ, wọn si ti lawọn ọmọọmọ pẹlu.

Leave a Reply