Ijọba Ogun yoo fi ẹṣọ Amọtẹkun lọlẹ ni Yewa

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ti kede pe ipinlẹ yii ti ṣetan lati gba abẹrẹ to n dena Korona ti yoo ti ọdọ ijọba apapọ wa, wọn ko si ni i pẹẹ maa fun awọn olugbe ipinlẹ yii lati dena aisan buruku ti wọn n pe ni Korona yii.

Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu kẹta yii, ni Gomina Abiọdun sọrọ yii l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta. O ṣalaye pe gbogbo ẹrọ firiiji tawọn yoo maa ko awọn abẹrẹ naa si lati tọju wọn gẹgẹ bo ṣe yẹ lo ti wa nilẹ. Bẹẹ lo ni gbogbo ilana to yẹ kijọba oun tẹlẹ lori awọn to yẹ ko kọkọ gba abẹrẹ naa ni ajọ ‘National Primary health Care Development Agency’ ti kọ awọn, eyi naa si ni pe awọn ẹṣọ eleto aabo ti yoo maa lọọ tọju awọn eeyan ni ki wọn kọkọ gba abẹrẹ idaabo bo naa.

Gomina sọ pe ile iwosan kereje ọọdunrun ni afojusun oun lati tun ṣe ki saa akọkọ yii too pari.

Lori ikọ Amọtẹkun ti ko ti i bẹrẹ nipinlẹ Ogun, Gomina Abiọdun sọ pe laipẹ yii ni wọn yoo fi ikọ naa lọlẹ. O ni Yewa ni yoo ti kọkọ bẹrẹ, nitori bo ṣe jẹ pe rogbodiyan ibẹ lo pọ ju ti ibi yooku lọ.

‘‘A ti fẹẹ pari iṣe lori igbani si ikọ Amọtẹkun ni Yewa. Mo mọ pe awọn to jẹ  ọmọ adugbo kọọkan ni wọn mu lati ṣiṣẹ nibẹ, ki i ṣe pe ki wọn lọọ mu ọmọ Ado-Odo-Ọta pe ko waa ṣiṣẹ l’Ọja-Ọdan, awọn eeyan to mọ agbegbe kọọkan daadaa la yan lati ṣoju adugbo wọn’’ Bẹẹ ni gomina wi.

O rọ awọn alaga afun-n-ṣọ lagbegbe kọọkan lati ni akọsilẹ eto iranwọ ijọba to ba n waye lọdọ wọn. O ni wọn gbọdọ ni akọsilẹ orukọ awọn ọkunrin, obinrin, awọn ọdọ atawọn to nilo iranlọwọ lagbegbe ti kaluku wọn n ṣoju.

Leave a Reply