Ijọba Ondo kilọ fun ẹgbẹ CAN: Ẹni to ba ṣe isọ-oru wọnu ọdun tuntun n fẹwọn ṣere.

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fa ibinu nla yọ latari ọrọ ti Alaga ẹgbẹ CAN nipinlẹ Ondo, Ẹni-Ọwọ John Ọladapọ, sọ lori ofin tijọba fi de isọ-oru aṣe wọ inu ọdun tuntun to fẹẹ waye lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, mọju Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.

Nigba to n fun Ẹni-Ọwọ ọhun lesi ọrọ rẹ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, Alaga igbimọ to n mojuto didena itankalẹ arun Korona nipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Adesẹgun Fatusi, ni ki i ṣohun to boju mu rara bi iransẹ Ọlọrun naa ṣe n gbo awọn araalu laya lati ṣe lodi si ofin ijọba.

O juwe igbesẹ ti pasitọ naa gbe bii eyi to le ṣakoba nla fun eto ilera ipinlẹ Ondo bi wọn ko ba tete mojuto o.

Ọjọgbọn Fatusi ni ofin konilegbele tijọba pasẹ rẹ lọjọ aisun ọdun ko ni nnkan an ṣe pẹlu ọrọ ẹṣin nitori pe ilera awọn araalu jẹ ijọba logun ju ohunkohun lọ. O ni idi ti wọn fi gbe ofin naa kalẹ ni ki wọn le tete dena itankalẹ arun Korona ẹlẹẹkeji to ti n gbilẹ kaakiri orilẹ-ede yii.

Ọga agba fasiti imọ iṣegun to wa niluu Ondo ọhun ni ijọba ko ti i yi ọrọ rẹ pada lori ofin konilegbele naa.

O ni ki ẹnikẹni to ba ti ru ofin Korona tete maa mura silẹ lati fẹwọn osu mẹta jura tabi ki onitọhun sanwo itanra ẹgbẹrun lọna ogun Naira, ni ibamu pẹlu abala kejidinlogun ninu iwe ofin.

Leave a Reply