Ijọba Ondo kọ lẹta s’Agboọla, wọn ni ko da awọn ẹru to wa lọwọ rẹ pada kiakia

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo ti kílọ fun igbakeji gomina tẹlẹ, Ọnarebu Agboọla Ajayi, lati tete da gbogbo ọkọ atawọn ẹru ijọba mi-in to ṣi wa lọwọ rẹ pada lẹyẹ-o-ṣọka.

Bo tilẹ jẹ pe lati inu oṣu keje, ọdun to kọja, ni Agboọla ti kẹru rẹ kuro nile ijọba, ti ko si fi bẹẹ da sọrọ iṣakoso ilu mọ latari ede aiyede to bẹ silẹ laarin oun ati ọga rẹ síbẹ, ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun yii, ni saa rẹ ṣẹṣẹ parí gẹgẹ bii igbakeji gomina.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ijọba ti kọkọ kọ lẹta kan si i lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 2020, iyẹn nigba to ku bii ọsẹ kan pere ki saa akọkọ oun ati Gomina Rotimi Akeredolu pari.

Ai ri esi kan pato lati ọdọ oludije ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ọhun lẹyin bii ọsẹ mẹta to ti kuro nipo lo mu wọn kọ omiiran si i lọsẹ yii, ninu eyi ti wọn ti tẹ ẹ mọ ọn leti pe o gbọdọ da awọn ẹru to ṣi wa ni ikawọ rẹ pada sọdọ ijọba ni kiakia.

Lara awọn ẹru ti wọn nijọba fẹẹ gba pada lọwọ Ọnarebu ọhun ni, ọkọ Toyota Land Cruiser SUV ati Toyota Hillux tuntun meji.

Leave a Reply