Ijọba ti fi katakata yanju iyooku ile to wo l’Ebute-Mẹtta, wọn ni ki lanlọọdu ile naa yọju kia

Faith Adebọla, Eko

Laika ti pe ayẹwo ṣi n lọ lori ohun to fa iṣẹlẹ ile alaja mẹta kan to ṣadeede wo lulẹ lapa kan lọsan-anSatide to kọja yii si, ijọba ti gbe katakata lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn si ti wo gbogbo awoku ile naa to wa lori iduro palẹ, bẹẹ ni wọn kede pe ki lanlọọdu ati abanikọle (difẹlọpa) to kọle naa yọju lati dahun awọn ibeere kan nipa iṣẹlẹ naa lọfiisi wọn.

Ọga agba fun ajọ to n ri si ọrọ pajawiri l’Ekoo (LASEMA), Dokita Olufẹmi Oke-Ọsanyintolu lo ṣo eyi di mimọ ninu atẹjade kan to kọ nipa iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun. Oke-Ọsanyintolu sọ pe ile naa ko ṣadeede da wo, ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin ni wọn ti kọ ọ, ati pe ami ti wa pe aarẹ ti mu ile ọhun, tori o ti di wo sara, o si ti lanu lawọn ibi kan tẹlẹ.

O ni awọn ile ti wọn kọ kun un ati awọn ṣọọbu ti wọn so mọ ọn loriṣiiriṣii lati fi pa’wo lai bitita fun ilera ati ipilẹ ile naa wa lara ohun to ṣokunfa bo ṣe da wo ọhun.

Tẹ o ba gbagbe, ori lo ko ọpọ awọn olugbe ile alaja mẹta ọhun yọ lopin ọsẹ to kọja yii nigba ti apa kan ile naa ṣadeede lanu hẹẹ, to si rọ lulẹ l’Ojule karundinlọgọrun-un, Opopona Cemetry, to wa ladojukọ ileewosan Comprehensive, l’Ebute-Mẹta.

Bo tilẹ jẹ pe ko sakọsilẹ pe ẹnikẹni doloogbe ninu ajalu naa, o kere tan, eeyan mẹta ni wọn ri fa yọ ninu awoku ile naa, alaboyun kan si wa lara wọn, to ti fara ṣeṣe yannayanna.

ALAROYE gbọ pe bawọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ọrọ pajawiri l’Ekoo, LASEMA, ati ajọ LASAMBUS, tileeṣẹ ọlọpaa Eko atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ṣe tete debi iṣẹlẹ naa lo mu ki wọn le doola awọn ti awoku ile naa ka mọ ọhun.

Wọn lawọn to fara pa naa ṣi n gba itọju nileewosan ijọba Comprehensive to wa nitosi naa.

Ọpọlọpọ miliọnu naira lawọn dukia ti wọn foju diwọn rẹ pe o ba iṣẹlẹ naa lọ latari bi awọn to n ṣe ka-ra-ka-ta ṣe kun isalẹ ile naa.

Leave a Reply