Ijọba ti gbẹsẹ kuro lori ofin konilegbele ni Kwara

Dada Ajikanje

Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ko si ofin konilegbele mọ nipinlẹ ọhun, bẹrẹ lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu yii.

Ọgbeni Rafiu Ajakaye, ẹni ti i ṣe akọwe gomina nipa eto iroyin lo fọwọ si ikede yii lori ikanni abẹyẹfo ijọba ipinlẹ ọhun.

Bakan naa ni ikede ọhun sọ pe awọn eeyan ipinlẹ naa yoo maa ri ọpọ mọto awọn agbofinro laarin ilu, ti wọn yoo maa lọ, ti wọn yoo maa bọ.

O ni eredii eyi ni lati pese aabo to peye laarin ilu, ki irufẹ ohun to ṣẹlẹ lasiko rogbodiyan SARS, tawọn eeyan kan lọọ n fọ sọọbu, ti wọn si n ja gbogbo ibi ti ijọba ko awọn ohun to le ṣe ilu lanfaani pamọ si.

Ijọba dupẹ lọwọ awọn raaalu fun ifarada wọn, bakan naa lo ki awọn ẹṣọ agbofinro fun iṣẹ takuntakun ti awọn naa n ṣe pẹlu.

Leave a Reply