Ijọba ti ko awọn akẹkọọ ileewe girama to n fa oogun oloro lọ sibudo awọn ọmọ alaigbọran

Faith Adebọla, Eko

Ijọba ipinlẹ Eko lawọn ọmọleewe marun-un ti wọn wa ninu fọran fidio kan to n ja ranyin lori atẹ ayelujara, nibi tawọn majeṣin naa ti n fa egboogi oloro pẹlu aṣọ ileewe lọrun wọn, ibudo ti wọn ti n tun ọmọ alaigbọran kọ ti wọn n pe ni Rehabilitation Center, lawọn ọmọ naa yoo ṣi wa, wọn o ti i le lọ sọdọ awọn obi wọn lasiko yii.

Oludamọran pataki lori eto ẹkọ si Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbọ Wahab, lo sọrọ yii fakọroyin wa lori aago lọjọ Iṣẹgun, nigba to n ṣalaye ibi tọrọ awọn ọmọ to huwa palapala ọhun de duro.

Tokunbọ fidi ẹ mulẹ pe lẹyin tawọn alaṣẹ ileewe Orẹyo Senior Grammar School, to wa niluu Igbogbo, lagbege Ikorodu, nipinlẹ Eko, ti juwe ọna ile obi wọn fawọn akẹkọọ onimukumu ọhun nijọba fi pampẹ ofin gbe wọn lati lọọ tun wọn kọ.

O ni igbesẹ yii ṣe pataki tori iwa tawọn ọmọ naa hu fihan pe ironu wọn ko daa to, wọn o si fiwa ọmọluabi han, afi kawọn ṣiṣẹ lori beeyan ṣe n ronu ati beeyan ṣe le yii ironu ọmọde pada si rere fawọn akẹkọọ wọnyi.

Ijọba Eko waa kilọ fawọn obi lati maa ṣe ojuṣe wọn pẹlu awọn ọmọ wọn deedee, tori ile la ti n ko ẹṣọ r’ode, ọdọ awọn obi si ni ibawi ati itọsanna awọn ogo wẹẹrẹ wọnyi ti bẹrẹ.

Sadeede ni fọran fidio kan to ṣafihan awọn ọmọleewe Oreyo SGS yii gori atẹ ayelujara, ti fidio naa si n ja ranyin. Bawọn eeyan ṣe n wo awọn akẹkọọ marun-un ninu ile akọku kan ti wọn n fa eefin egboogi oloro sagbari ninu okun rọba kan ti wọn n pe ni ṣiṣa ya ọpọ eeyan lẹnu, paapaa latari pe akẹkọọ-binrin lawọn ọmọ ọhun.

Fidio yii la gbọ pe wọn ta latare de ọdọ awọn alaṣẹ ileewe ti wọn fi wa awọn ọmọ naa lawari, ti wọn si da sẹria fun wọn, wọn ni ki wọn ṣi lọọ fidi mọle wọn na.

Leave a Reply