Ijọba ti mu awọn ti wọn lọọ ṣakọlu sile Adajọ-binrin Odili l’Abuja

Faith Adebọla

 Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa ni ọwọ awọn ti tẹ gbogbo awọn to lọọ ṣakọlu sile ọkan lara awọn adajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Adajọ-binrin Mary Odili, lopin ọsẹ to kọja yii.

Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa, IGP Alkali Usman, lo fidi eyi mulẹ niluu Eko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, lasiko to sọrọ nibi eto idanilẹkọọ akanṣe ọlọjọ meji fawọn agbofinro ipinlẹ Eko ati Ogun, lagbegbe Victoria Island.

Ṣaaju ni ọga agba pata ọhun ti sọ l’Abuja lọjọ Aje, pe awọn maa bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ akọlu to waye ọhun, awọn si maa fimu awọn to ba jẹbi ọrọ ọhun danrin.

Usman ni “Mo ti fẹsọ wo ṣaakun gbogbo ohun to n ṣẹlẹ, tori ẹ ni mi o ṣe fẹẹ sare sọrọ lori ẹ, tori oju lagbalagba n ya, agba ki i ya’nu, ati pe ohun tawọn ọmọ Naijiria n reti lati gbọ ni ibi ta a ba’ṣẹ de lori iṣẹlẹ ọhun, wọn fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an ati ohun ta a ṣe lori ẹ.

Ohun to da mi loju ni pe a ti fi pampẹ ofin gbe awọn to lọwọ ninu iwakiwa yii, a si ti n ṣewadii lẹnu wọn, a fẹẹ mọ ohun ti wọn ri lọbẹ ti wọn fi waro ọwọ bẹẹ. Lẹyin iwadii la maa mọ igbesẹ to kan.”

Tẹ o ba gbagbe, awuyewuye nla lo da silẹ nigba tawọn agbofinro kan ti wọn ni ọtẹlẹmuyẹ DSS tijọba apapọ ni wọn, lọọ ya bo ile Abilekọ Odili, ti i ṣe iyawo gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Peter Odili, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, niṣẹlẹ naa waye.

Bi agbọn ṣe n sẹ lori iṣẹlẹ yii, bẹẹ ni ikamudu n sẹ, Minisita feto idajọ, Abubakar Malami, loun o mọ nnkan kan nipa ẹ, ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lawọn o ran ẹnikan niṣẹ, bẹẹ lawọn EFCC ni ki i ṣawọn, ko too waa di pe ọwọ tẹ awọn eeyan naa gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ilẹ wa ṣe sọ.

Leave a Reply