Ijọba ti n da ẹru tawọn janduku ji ko pada fawọn to ni in l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ṣagbatẹru gbigba ati dida awọn ẹru ti awọn janduku kan ji lopin ọsẹ to kọja pada fawọn ẹlẹru bẹrẹ iṣẹ wọn.

Akọwe igbimọ naa, Ọgbẹni Samson Owoyọkun, ṣalaye fawọn oniroyin pe ijọba ibilẹ mẹrinla ni wahala naa ti waye. O ni awọn ti wọn ni awọn ẹru naa ti n mu ẹri idaniloju wa lati gba ẹru wọn.

Lara awọn nnkan ti awọn janduku naa ti da pada ni firiiji, ẹrọ ilọta, tẹlifiṣan, jẹneretọ, aga onigi, aga onike ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Akọwe ileeṣẹ adojutofo lẹka eto ilera to jẹ tijọba, Osun Health Insurance Scheme, Dokita Niyi Ọginni, sọ pe oun ti ri ida mẹẹẹdogun ninu ida ọgọrun-un nnkan ti wọn ji nileeṣẹ oun.

O rọ awọn araalu lati ma ṣe bo ẹnikẹni ti wọn ba ka ẹru ijọba mọ lọwọ laṣiiri rara.

Leave a Reply