Ijọba ti tun fi kun owo epo bẹntiroolu o!

Faith Adebọla

Ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii ni ileeṣẹ to n mojuto tita epo bẹntiroolu nilẹ wa, iyẹn Petroleum Product Marketing Company to wa labẹ akoso ileeṣẹ elepo ilẹ wa, NNPC kede pe afikun yoo ba owo ti wọn n gbe epo jade lati dẹpo. Dipo aadọjọ din mẹta naira (147.67) ti wọn n ta a tẹlẹ, marunlelaaadọjọ ati kọbọ mẹtadinlogun (155.17) ni wọn yoo maa ta a bayii.

Bi o ba si le ba iye yii wa lati ibi ti wọn ti n gbe e, a jẹ pe mejidinlaaadọsan-an naira si aadọsan-an naira (168) si (170) ni wọn yoo maa ta jala epo kan bayii gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ri si tita epo bẹntiroolu ṣe sọ.

Nileepo Amuf Oil ati Total to lagbegbe Ikosi t’ALAROYE ṣabẹwo si laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, niṣe ni wọn ti yi ẹrọ wọn kuro niye ti wọn ti n ta a tẹlẹ, wọn sun onka ẹrọ wọn soke si aadoje naira ọhun. Awọn ileepo mi-in ko si ta epo rara, wọn lawọn n duro de ẹnjinnia to maa ba awọn yi ẹrọ wọn soke.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọga agba lẹka itaja nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ epo tita nilẹ wa, PPMC ni wọn lo fi lẹta kan sọwọ si ajọ to n ṣakoso ọrọ epo rọbi nilẹ wa, NNPC, lọjọ kọkanla, oṣu yii. Ninu lẹta naa lo ti dabaa pe ki wọn fi kun owo tawọn olokoowo epo yoo maa gbe kinni ọhun jade lati awọn Dẹpo epo kaakiri orileede yii. O ni dipo aadọjọ din mẹta naira ati kọbọ mẹtadinlaaadọrin (#147.67) ti wọn n gbe lita epo jade tẹlẹ, ki wọn bẹrẹ si i ta a fun wọn ni naira marunlelaaadọjọ ati kọbọ mẹtadinlogun (#155.17)

Lẹta naa tẹsiwaju pe, bẹrẹ lati ọjọ kẹtala, oṣu kọkanla yii, iye ti awọn olokoowo yoo maa ta epo bẹntiroolu fawọn onimọto ati araalu le wa laarin naira mejidinlaaadọsan-an (#168) si naira mẹtalelaaadọsan-an (#173).

Tẹ o ba gbagbe, inu oṣu kẹsan-an, ọdun yii, nijọba apapọ lawọn ti yọpa yọsẹ kuro ninu iranwọ owo-ori epo tawọn n ṣe tẹlẹ, ti wọn n pe ni sọbusidi (subsidy), pe iye ti epo ba ba de lati ibi ti wọn ti lọọ fọ ọ nibaamu pẹlu iye towo epo ba jẹ lọja epo agbaye laraalu yoo maa ra a.

Minisita fọrọ epo rọbi, Timipre Sylva, sọ nigba naa pe irọrun ati anfaani lo maa ja si faraalu ti wọn ba le gba a wọle, latigba naa si ni ẹkunwo ti n ba iye ti wọn n ta epo, paapaa epo bẹntiroolu.

Leave a Reply