Ijọba yoo ṣi awọn ileejọsin loṣu to n bọ nipinlẹ Ogun– Dapọ Abiọdun

Adefunkẹ Adebiyi, Ogun

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ogun, Omọọba Dapọ Abiọdun, kede lọfiisi ẹ I’Okemosan, l’Abẹokuta, pe ẹwọn oṣu mẹfa lẹni tọwọ ba tẹ pe ko lo ibomu lasiko yii yoo ṣe.

Bakan naa lo ni ileejọsin yoo di ṣiṣi lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ.

Awọn akẹkọọ to wa nipele aṣekagba nileewe girama naa yoo wọle lọjọ kẹrin, oṣu kẹjọ, ṣugbọn awọn ọmọleewe yooku ko ni i ti i wọle ni tiwọn.

O fi kun un pe  gbogbo ofin to de Korona gbọdọ wa ni pipamọ nibi gbogbo.

.

Leave a Reply