Ika ati ọdalẹ ni Oyetọla, ọdun mẹrin pere lo maa lo l’Ọṣun – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe aṣiṣe nla ni oun ṣe lati gbe eeku ida iṣakoso ipinlẹ Ọṣun le Gomina Gboyega Oyetọla lọwọ.

O ni oju oun ti la kedere bayii pe ika ati ọdalẹ ni Oyetọla pẹlu bo ṣe ba gbogbo iṣẹ rere ti gbogbo awọn jọ fi ọdun mẹjọ ṣe nipinlẹ Ọṣun jẹ.

Niluu Ikire ni Oyetọla ti sọrọ naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba to lọọ fi Alhaji Moshood Adeoti han wọn gẹgẹ bii oludije ti igun TOP fẹẹ lo fun idibo gomina.

Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe odidi ọdun meji loun fi bẹ Gomina Oyetọla lẹyin to di gomina, bẹẹ ni oun tun ran awọn eeyan si i lati ba oun bẹ ẹ, sibẹ, o ni ọkunrin yii ko gba, ṣe lo pinnu lati sọ oun lorukọ buruku lọdọ awọn araalu.

O ni iwe ofin ẹgbẹ awọn faaye silẹ pe ki awọn paarọ gomina ti ko ba ṣe daadaa lẹyin ọdun mẹrin, asiko idibo abẹle si lawọn ọmọ ẹgbẹ atawọn adari ẹgbẹ yoo fi ibo wọn le iru gomina bẹẹ danu, eleyii lawọn yoo si ṣe fun Oyetọla ninu idibo ti yoo waye lọla Satide.

Arẹgbẹṣọla sọ siwaju pe, “Latigba ti Oyetọla ti di gomina lo ti gbogun ti mi bii ẹni pe mo ṣe e nijamba ri. O ni mi o fẹ ki oun di gomina, mo sọ pe mo ti gbọ, ṣugbọn ni bayii to o ti di gomina, ki lo tun fẹẹ da?

“Odidi ọdun meji ni mo fi bẹ ẹ, mo sọ fun un pe araye o gbọdọ yọ wa, mo ni oko iparun lo n lọ yii. Gbogbo ẹmi mi ni mo fi sin ipinlẹ yii, mo tun ṣiṣẹ fun Oyetọla ko le di gomina lẹyin mi. Nigba ta a wa fun ipolongo ibo rẹ nibi, lati aafin Akire ni ojo ti pa wa titi debi ti a wa yii.

“Bo ṣe di gomina lo sọ mi di ọta rẹ, awọn ti wọn jọ dupo lasiko idibo abẹle lo ko mọra to fi n ba mi ja. Mo bẹ ẹ pe ti ko ba tiẹ fẹran mi, ko ma ba gbogbo iṣẹ ti mo ṣe silẹ jẹ, sibẹ, ko gbọ”

Arẹgbẹṣọla waa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati gba ẹgbẹ silẹ lọjọ Satide, ki wọn fi ibo wọn yan Adeoti gẹgẹ bii oludije ẹgbẹ APC ninu idibo oṣu keje, ọdun yii.

Leave a Reply